World Cup 2018: Denmark na Peru pẹ̀lú àmì ayò 1-0

Peru
Àkọlé àwòrán Ikọ Peru gbiyanju lọpọlọpo ninu ifesewonse naa, amo Denmark lo jawe olubori nigbati Yussuf Poulsen sọ bọọlu sinu awọn.

Ikọ orilẹede Denmark bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ alakọkọ pẹlu ikọ Peru ninu idije Ife Ẹyẹ Agbaye ti Russia 2018 pẹlu ami ayo eyokan si odo.

Ikọ Peru sọ bọọlu kọjú-sími-gbáa-sílé nu, pẹlu ọpọlọpọ anfaani lati gba bọọlu wọ inu awọn.

Peru gbiyanju lọpọlọpọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, amọ Denmark lo jawe olubori nigbati Yussuf Poulsen sọ bọọlu sinu awọn ni isẹju mọkandinlọgọta ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRussia 2018: Nàìjíríà dúró gìdìgbà, ki Ọlọrun fún wa ṣe

France ni ikọ Peru yoo ma a koju, nigbati Denmark yoo ma fẹsẹwọnsẹ pẹlu Australia lẹyin ti wọn ti gba ami ayo mẹta lori atẹ isori kẹta ti Ife Ẹyẹ Agbaye Russia 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbolahan Kabiawu: Fífi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ dára fún ẹ̀yà ara