Visionscape: Ìpínlẹ̀ Èkó ló gba àwọn 300 tí wọn dádúró

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Ile-ise kolẹkodọti ko sisẹ to l’Eko’

Ọpọ eniyan lo n fi ero wọn han lori awọn ọọdurun awọn adari awọn agbalẹ ti wọn da duro ni ipinlẹ Eko.

Awuyewuye naa da lori pe se ile isẹ agbalumo, Visionscape Sanitations Solution, VSS tabi ijọba ipinlẹ Eko lo le awọn osisẹ naa.

Iwe Iroyin News Agency of Nigeria jabọ pe Visionscape ni awọn kọ ni wọn gba awọn osisẹ naa si isẹ, ati wipe Ajọ ‘Clean Lagos Initiative’ labẹ isejọba ipinlẹ Eko lo gba wọn si isẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lórí ìgbéyàwó mi, ẹ̀ ṣáà jẹ́ kó wà báyìí'

Amọ, oludamọran fun gomina ipinle Eko lori ọrọ Ajọ CLI sọ pe ijọba ko ni nkan se pẹlu idaduro awọn osisẹ naa, ati wipe ajọ CLI ko si labẹ ijọba ipinlẹ Eko.

Ipa wo ni idaduro awọn ọọdunrun agbalẹ ipinlẹ Eko ni lara ilu?

Laipẹ yii ni awọn agbálẹ̀ ní ilu Ékó fẹ̀hónú hán ní ọ́fììsì Visionscape pẹlu ẹsun pe Visionscape kò san owo oṣù wọn déédé àti pé wọ́n n yọ owó oṣù wọn láì sí àlàyé kankan.

Amọ, Olórí ẹ̀ka ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún iléesẹ́ Visionscope ní ìpínlẹ̀ Èkó, Motunrayọ Elias, nínú ifọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC Yorùbá ní, iléesẹ́ Visionscape kọ́ ló gba àwọn agbálẹ̀ tó fi ẹ̀hónú hàn láìpẹ́ yìí sí isẹ́, nítorí náà, kìí se iléesẹ́ Visionscape ló jẹ wọ́n lówó osù.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionVisionscape: Abẹ́ illéesẹ́ wa kọ́ làwọn agbálẹ̀ wà

Oseese ki iru isẹlẹ yii lọpọ igba da oṣi ati iṣẹ silẹ ni awujọ, ati aisi igbesoke ni igbe aye awọn eniyan ni awujọ.

Bakan naa, bi ayika ba dọti, aini imọtọtọ to peye le fa aisan ati ajakalẹ aarun ni iru ilu nla bii ti ipinlẹ Eko.

Lai fa ọrọgun, bi ayika ba dti, ọrọ aje iru agbegbe ati orilẹede bẹẹ ko le e gbe pẹẹli soke.