Agbẹnusọ ọlọ̀pàá: Afurasí tó sekú pa Igwe ilẹ́ Enugu fojú winá òfin

Àwòran abúlé Ọgbọzinne ní ìpínlẹ̀ Enugu
Àkọlé àwòrán Ìbànújẹ́ ní Ọgbọzinne lẹ́yín ikú Igwe Stephen Nwatu.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu Ebere Amarizu, sọ pe awọn ti mu afurasi kan lori iwaadi lati mọ awọn to ṣ'eku pa Igwe Stephen Nwatu.

O fi kun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ọlọpaa ko tii ṣetan lati kede orukọ afurasi naa.

Amarizu sọ pe afurasi ọhun n ran awọn ọlọpaa lọwọ lori iwaadi awọn to f'ẹmi Igwe Nwatu ṣofo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lórí ìgbéyàwó mi, ẹ̀ ṣáà jẹ́ kó wà báyìí'

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa naa sọ pe idakẹji ti wa bayii ni ijọba ibilẹ Guusu Nkanu ni ipinlẹ Enugu nibi ti iṣẹlẹ iṣekupani ti ṣẹlẹ.

Iwaadi awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

Related Topics