Ẹniọla Badmus: Bí mo ṣe fẹ́ wà nìyìí

Ẹniọla Badmus Image copyright ENIOLA BADMUS/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Ẹniọla Badmus jẹ́ mọ̀lúmọ̀ká òsèré

Eniola Badmus jẹ́ òsèré Nollywood ọmọ Nàìjíríà. Ọdún 2008 ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí mọ̀ ọ̀ lẹ́yìn tó fara hàn nínú eré Jenifa.

Ọmọ bíbí Ijẹbu Ode, ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Ogun ni Eniola Badmus. Ìlú kan náà ni ó ti lọ ilé ìwé girama.

Lẹ́yìn èyí, ó tẹ̀síwájú lọ sí Fásitì ti ìlú Ìbàdàn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Tíátà ó sì tún gba oyè gíga Msc. nínú ìmọ̀ ọrọ̀ ajé (Economics) ní ilé ìwé gíga Fásitì ti ìlú Eko.

Ọmọ ogójì ọdún ni ó jẹ́, a bí i ní ọjọ́ keje osù kẹ́san, ọdún 1977.

Ó ti kópa nínú fíìmù bíi Jenifa, Gone to America, Divorce Not Allowed, Ghetto Bred àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó ti gba onírúurú àmì ẹ̀yẹ níle àti lẹ́yìn odi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lórí ìgbéyàwó mi, ẹ̀ ṣáà jẹ́ kó wà báyìí'

Òsèré Yorùbá, Ẹniọla Badmus ti fara hàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò Yorùbà tó fi mọ́ àwọn fíìmù tí wọn se lédè gẹ̀ẹ́sì.