AAUA; Ọ̀pọ̀ ìgbà ni SARS ma ń lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì wa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAAUA; Ọ̀pọ̀ ìgbà ni SARS ma ń lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì wa

Awọn akẹẹkọ fasiti Adekunle Ajasin, AAUA ti fi ẹsun kan awọn ọlọpa SARS wi pe wọn ja wọ ile ibusun wọn, ti wọn si lu awọn akẹẹkọ bi ẹni lu bara.

Iṣẹ awọn ọlọpaa SARS ni lati gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ paapa julọ lati daabo bo awọn ara ilu lọwọ awọn adigunjale.

Adari awọn akẹẹkọ fasiti naa, Ọlawale Ijanusi nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ wi pe, igba akọkọ kọ niyi ti awọn ọlọ́pàá ọtẹlẹmuyẹ naa n lu awọn akẹẹkọ bi bara, ti wọn yoo si fi panpe ọba mu wọn lori ẹsun pe wọn wọ asọ ju, eyi to mu wọn fara jọ awọn ọmọ yahoo-yahoo.

Ninu ọrọ tirẹ, Agbẹnusọ fun ile iwe fasiti Akungba, Shola Imoru sọ pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, ati wi pe eto aabo to peye wa fun awọn akẹkọọ fasiti naa, sugbọn isẹlẹ naa waye ni awọn ibugbe to wa ni ita ọgba ile iwe naa.

Amọ, agbenusọ fun ile isẹ ọlọọpa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph sọ pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori isẹlẹ naa.

Arakunrin Joseph wa rọ awọn ọmọ ile iwe fasiti Akungba ti o faragba nibi isẹlẹ naa, ati awọn ti o soju wọn lati wa si agọ ọlọọpa fun ẹri nitori ko tii si ẹri wi pe awọn ọlọ́pàá SARS naa fi iya jẹ akẹkọọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAgbenusọ fun ile isẹ ọlọọpa ni ipinlẹ Ondo ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori isẹlẹ naa.

Laipe yii ni awọn ọlọpaa Naijiria kede awọn nọmba ti awọn eeyan le pe wọn sori ẹ bi awọn ọlọpaa SARS ba n dunkoko mọ wọn.