Algeria: A gbẹ́sẹ̀ lé ayélujára láti dènà màgò-mágó ìdánwò

Nouria Benghabrit Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àsìkò ti tó kí a fòpin si ìwà ìbàjẹ́ lásìkò ìdánwò

Kò sí ǹkan tíjọba wa kò ni ṣe láti tọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa sọ́nà to yẹ ni ìran yìí.

Orilẹ-ede Algeria ti gbogbo ọna ayelujara wọn pa fun ẹrọ alagbeka ati foonu ori tabili fun wakati kan, kí danwo girama tó ba bẹrẹ, ki idanwo naa ma baa jade sita ṣaaju asiko rẹ̀.

Nouria Benghabrit, to jẹ minista fun eto ẹkọ, lo ṣe ikede pe, eyi yoo wa lati ogunjọ oṣu yii si ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keje ọdun yii, ti idanwo naa yoo pari.

Ijọba Algeria ni àwọn gbe igbesẹ yii lataari bi ibeere fun idanwo ṣe jade sita ṣaaju ọjọ idanwo lọdun 2016 lati inu ẹrọ ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nouria Benghabrit ni koda, wọn yoo tun di oju òpó facebook àwọn eniyan ni gbogbo asiko yii, lai yọ awọn akẹkọọ ati olukọ wọn silẹ rara.

Àkọlé àwòrán 'A gbọdọ ran awọn akẹkọọ wa lọwọ lati fopin siwa ibajẹ jiji iwe wo ninu idanwo'

"Lẹyin ti awọn alaṣẹ ti rii pe, awọn akẹkọọ n ji ìwe wo ṣaaju idanwo, ni a ti fopin si lilo ayelujara fétò ibara ẹni sọrọ tẹlẹ".

Arabinrin Benghabrit gba pe, igbesẹ yii ko ni tẹ awọn miran lọrun Sugbọn ó ní ó di dandan nitori ọjọ iwaju awọn akẹkọọ Algeria.

Ni ipari, minista fun eto ẹkọ naa ni, awọn yoo ṣamulo awọn Kamẹra ni gbogbo ibudo idanwo kaakiri Algeria.

O le diẹ ni ẹẹdẹgbẹrin awọn akẹkọọ ti won yoo kopa ninu idanwo aṣekagba girama yii.