South Korea: Èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ajá mọ́

Ẹran aja Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mase jaja mọ

Ile ẹjọ kan ti pase ki wọn ma pa aja fun ẹran jijẹ mọ̀ ni ilu South Korea.

Idajọ̀ naa jẹ ohun to jẹ idunnu fun awọn ajafẹtọ ẹranko. Wọn ni wipe eyi yoo sọ ẹran aja jijẹ di ohun itan ni ilu naa.

Ẹran aja je ounjẹ pataki ni South Korea lati ọjọ pipẹ, ti wọn si ma n jẹ to aja milionu kan lọdọọdun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Èèwọ̀ ẹ ò gbudọ̀ jajá mọ́

Saaju asiko idajọ yi, jijẹ ẹran aja ko wọpọ mo ni ilu naa nitori awọn ara ilu naa ti n sọ aja di nkan osin.