Nàìjíríà ní Russia ń ṣàfihàn ayọ̀ ṣáájú ìdíje Super Eagles

Nàìjíríà ní Russia ń ṣàfihàn ayọ̀ ṣáájú ìdíje Super Eagles

Ko si ibi ti ọmọ Nàìjíríà lọ ti wọ́n gbàgbé àṣà sílé rí!

Ọgbẹni Ayọdele Ogunmilọrọ, ọ̀kan nínú àwọn alatilẹyin fun Super Eagles Nàìjíríà ń fi ìrètí ṣafihan irufẹ ijó ti awọn ọmọ Naijiria to wa ni Russia bayii maa jo lalẹ òní lẹyin idije.

Èrò pé lé awọn ololufẹ Naijiria lori lasiko ti wọn n ṣafihan aṣa ìran wọn ni Russia nibi ti idije ife ẹyẹ agbaye tọdun 2018 ti n lọ lọ́wọ́.

Ikọ agbabọọlu Super Eagles to n ṣoju Naijiria yoo waako pẹlu orilé-ede Iceland laago meje lalẹ oni lẹyin ti Croatia ti fagba han Argentina pẹlu ami ayo mẹta sodo lalẹ ana ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ ni Russia.

Aṣa awọn ọmọ Naijiria ni lati maa fijo ati ayọ pa ìrònú rẹ́.

Ireti gbogbo ọmọ Naijiria nile ati ni Russia ni pe idunnu yoo ṣubu layọ wọn lẹyin idije Naijiria pẹlu Iceland ati Argentina to ku ni abala yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: