Fídíò ọmọ Adeboye tó dá wàhálà lẹ́ rèé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Leke Adeboye: Àwọn aláwáda kan fẹ́ irànlọ́wọ́ iléèwé

Leke Adeboye tó jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ baba rẹ̀, pásítọ̀ Enoch Adeboye, olórí ìjọ RCCG, gbé fídíò kan jáde nínú èyí tó bẹnu àtẹ́ lu àwọn tóm máa ń wá ilé ìjọsìn náà fun ìrànlọ́wọ́ owó àti ìrànlọwọ lílọ ilé ìwé.

Nínú fídíò náà tó gbé jáde lóri Facebook, Leke gba àwọn tí kò lágbára láti ra ounjẹ kií wan lọ sisẹ́ àgbẹ̀.

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà bó ọ́pọ́lọ́pọ̀ èniyàn nínú.

Kò pẹ́ tí fídíò náà jáde ni sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Daddy Freeze fésì sọ́rọ̀ náà, tó ní kí Leke fi oun tó n bẹ nínu banki ṣọ́ọ́ṣì RCCG han gbogbo ayé.

Kí ni èrò yín lórí ọ̀rọ̀ yí?