APC Convention: Níbo ni kárá ìlú gbà ní Abuja lónìí?

Awọn akopa nibii ìpàdé
Àkọlé àwòrán Ètò gbogbo ti tò fún ìpàdé APC nílùú Abuja lonii

Pẹ̀lú òjò wẹliwẹlí tó gbòdee ní ìlú Abuja, àwọn ènìyàn ti ń lọ síbi ìpàdé ìpádé àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọ́ṣèlú APC tó ń wáyé ní Eagle Square.

Ní ibi ìpàdé ọ̀hún ní wọ́n ó ti máa yan àwọn ti yóò sojú ẹgbẹ́ fún ọdún mẹrin mííràn láti darí.

Image copyright Gloria adagbon/twitter
Àkọlé àwòrán ìkìlọ̀ fún àwọn àwakọ̀ nílùú Abuja

Ní báyìí ìgbìmọ̀ elétò fún ìpàdé náà ti fi atẹjade síta f'àwọn ènìyàn tó ń wọ ìlú Abuja.

Àtẹjade naa juwe pé gbogbo ọkọ̀ tó bá ń bọ̀ láti òpópónà Sheu Shagari yóo gba ọ̀nà Ralph Sodeinde lẹ́ba Bullet Building to fi já sí Central Business District.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n tún ni àwọn máa dári ọkọ̀ láti òpópónà Kur Mohammed tàbí Constitution Avenue lẹ́gbẹ̀ Benue Building láti já sí Central Business District.

Kayode Opeifa to jẹ akọ̀wé Ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ìgòkègbodo ọkọ̀ nílù Abuja sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rísí ìdári ọkọ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò míràn ti wa lẹnu iṣẹ láti mójú tó àwọn súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyìn, ati ìmọ̀ràn fún Super Eagles