Àwọn ajínigbé: 'Ẹ mú N20m wá tàbí ká pa ìyàwó ọba'

Ẹgbẹ̀rún kan owo Nàìjírìa

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Jíjínigbé wọ́pọ̀ l'ágbègbè Niger Delta

Awọn ajinigbe ti wọn ji iyawo Ọba Alauga ti ilu Auga-Akoko ni Ipinlẹ Ondo ti beere fun ogun miliọnu owo naira(N20 million) ki wọn to le fi silẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ajinigbe naa lo kan si ẹbi iyawo Ọba naa Olukemi Agunloye.

L'ọ́jọ́ Aiku ni wọn ji obinrin naa gbe pẹlu awakọ rẹ ni opopona Augu-Ise si Akoko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ayédèrú Jẹẹsí Nàìjíríà ń tà wàràwàrà lọ́jà

Ijinigbe ti wa di ohun to wọpọ lorilẹede Naijiria, atiwipe ogbontarigi ajinigbe ni, Chukwudumeme Onwuamadike aka Evans, lo yọ̀ju si ileẹjo ni Ọjọru, Osu Kẹfa ọdun yii lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lọdun to kọja ni ile nla rẹ ni Magodo.