Ọlọ́pàá mú afunrasí mẹ́ta ní ilé òòṣà OPC l'Ekòó

Oga olopaa Eko, Edgal Imohimi Image copyright Lagos State Police Command
Àkọlé àwòrán Edgal Imohimi lọ ṣaaju ikó to lọ ile ooṣa naa

Ile iṣẹ ọlọpàá Ipinlẹ Eko ti rí ile ooṣa kan ni Opebi, Ikeja nibi ti wón ni ẹgbẹ OPC ti maa ń dájọ fun awọn ti wọn ba f'ẹsun kan ti wọn yoo si da sẹ̀ria fun wọn.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Edgal Imohimi lọ ṣaaju ikó to lọ ilé òòṣà naa ni bi ti wọn ti ri ẹrọ agbowó (POS) mẹta.

Awọn afunrasi mẹta ni ọlọpaa gbamu ni ile òòṣà naa.

Edgal ni wọn yoo ṣ'alaye oun ti POS n ṣe ni ile ooṣa nitori iwadii fi han pe awọn adigunjale naa maa ń gbe ẹrọ agbowọ naa kaakiri ti wọn ba ti lọ ṣọṣẹ lati fi tipatipa gba owo lọwọ awọn to ba wọ panpẹ́ wọn.

Ọga ọlọpaa naa ni oun ni igbagbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC maa n fi tipatipa mu awọn ti wọn ba fa wa s'ile ooṣa naa mọlẹ̀.

Edgal ni ṣe lo yẹ ki awọn ọmọ ẹgbe OPC maa fa ẹnikẹni ti wọn ba mú lé ọlọpaa lọwọ.