Ìkọlù Plateau: Àwọn ológun ṣ'àfihàn afurasí apànìyàn mẹ̀ta

Awọn ologun nyan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileto Mọkanla ni wahala ikọlu naa ti waye

Ologun ti ṣe afihan awọn afurasi mẹta ti ọwọ awọn ologun tẹ lori ikslu ipaniyan to waye ni opin ọsẹ to kọja ni ileto mọkanla nipinlẹ Plateau.

Darandaran ni meji ninu awọn afurasi naa ti ọkan yooku si jẹ ọmọ ẹya Berom, ọkan lara awọn ẹya to n ba awọn fulani forigbari lagbegbe naa lori aye ijẹko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikọ ọmọogun kogberegbe ti n ṣeto akanṣe abo lagbegbe naa ni wọn mu awọn afurasi naa ti wọn si fi oju wọn han faraye ri ni ọjọọru ni ilu Jos pẹlawọn mẹrinla miran ti ọwọ tẹ lori ipaniyan lagbegbe naa.

Alukoro fun ikọ ọmọogun kogbregbe naa,Ọgagun Umar Adams ni ọwọ ba awọn afurasi naa pẹlu ibọn wọn.

Àkọlé àwòrán eeyan mẹrindinlaadọrun ni awọn amookunṣika kan pa nipinlẹ Plateau ni opin ọsẹ to kọja

Ibọn gigun mẹrin, ibọn ilewọ mẹta pẹlu ibọn atamatase AK47 kan ni wọn ba lọwọ awọn eeyan naa.

O ni wahala to n waye kaakiri ipinlẹ naa ni ẹnu lọwọlọwọ yii lo gbe awọn mẹrinla yooku ti wọn tun ṣe afihan wọn de ahamọ.