Àwọn t'Ojuẹlẹgba l'Eko sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ oògùn olóró lára

Àwọn t'Ojuẹlẹgba l'Eko sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ oògùn olóró lára

Wo bí oògùn olóró ṣe ń fèèyàn dábírà!

BBC Yoruba bá díẹ̀ lara àwọn to n lo oogun oloro nibudokọ 'Under Bridge' ni Ojuẹlẹgba nipinlẹ Eko sọrọ lori àṣilo oogun oloro.

Awọn eeyan ìdíkọ̀ naa gba pe iṣẹ́ burúkú ni oògùn olóró n ṣe lara wọn.

Wọn mẹnuba oriṣii ọna ti onikaluku wọn n gba lo oogun oloro ati orukọ irufẹ eyi ti wọn n mu.

Oògùn olóró, ọmọ ìyá Codeine

Orilé-ede Naijiria ti fofin de gbigbe Codeine wọle lẹyin iwadii ile iṣẹ wa (BBC) lori bi àwọn ọdọ ṣe n ṣìí lo.

Ṣugbọn igbesẹ yii nikan kọ lo le fopin si àṣìlò oogun oloro ni Naijiria.

Awọn dokita to n ba awọn to n lo oogun oloro sọrọ ni Ojuẹlẹgba naa mẹnuba ọna abayọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ àwọn ọ̀dọ́ lo ti lùgbàdì aṣilo oogun nipa ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti àìní àbójútó àwọn òbí ati alagbatọ.

Bẹẹ, Yoruba gbà pé, ọmọ ti a kò tọ́ ni yoo gbe ilé ti a kọ́ tà lẹyin ọ̀la.