Awakọ̀ Ekó: Kò sí ǹkan tó jọ ọ̀nà tuntun fún ọkọ̀ ńlá

Afara Eko Bridge
Àkọlé àwòrán,

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ní àwọn ti yan àwọn ọ̀nà tuntun fún àwọn awakọ̀ epo lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ epo bẹtirol

Awọn awakọ ọkọ nla to wa ni ipinlẹ Eko ti sọ wi pe awọn ko gbọ nkankan nipa ọna tuntun fun awọn awakọ.

Ni opin ọsẹ ni ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ti yan àwọn ọ̀nà tuntun fún àwọn awakọ̀ epo nípìnlẹ̀ Èkó, gẹ́gẹ́ bíi ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ epo bẹtiro to gba ẹ́mí ọ̀pọ̀ ènìyan tí ọ̀pọ̀ dúkìá náà sì ṣòfò pẹ̀lú.

Awọn awakọ to ba BBC News Yoruba sọrọ ti ko fẹ ka darukọ wọn ni ko si ọna kan pato fun awọn awakọ nla, nitori naa ni wọn se wa loju ọna tọ já afárá Eko bridge si àpápá.

Àkọlé fídíò,

Awakọ̀ Ekó: Kò sí ǹkan tó jọ ọ̀nà tuntun fún ọkọ̀ ńlá

Wọn fikun pe ijọba o tii fi iwe sita fun awọn awakọ lori ofin tuntun naa.

Ti a ko ba gbagbe, ẹmi mẹsan ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹrinlelaadọta lo lọ nibi ijamba to sẹlẹ ni opopona marosẹ Ibadan si Eko nigba ti ọkọ agbepo kan susu lule to si gbana.