Ìjàmbá iná Èkó: Àwọn ẹbí ti n farahàn ní fún àyẹ̀wò DNA

Awọn ọkọ to jona

Oríṣun àwòrán, LASEMA/TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Eniyan mejila lo ku ninu ijamba naa.

Ayẹwo DNA lati da awọn to ku ninu ijamba ina to ṣẹlẹ ni Eko ni Ọjọbọ to kọja ti bẹrẹ bayii ni ile iwosan ijọba to wa ni Ikeja, LASUTH.

BBC gbọ pe awọn ẹbi awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa ti lọ n foruko silẹ ni ileeṣe to n koju iṣẹlẹ pajawiri ni Ipinlẹ Eko, ti wọn si tun lọ si ile iwosan LASUTH ni Ikeja lati lọ fi ẹjẹ silẹ.

Ẹjẹ yii ni yoo jẹ ko ṣeeṣe lati jẹ ki wọn ṣe ayẹwo DNA. Lẹyin naa ni wọn yoo le gbe awọn oku fun ẹbi wọn.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba Ipinlẹ Eko ni awọn n gbe ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìrìnà àwọn ọkọ̀ epo loju popo

Ọjọ Aje ni Kọmiṣọna fun Eto Ilera Dokita Jide Idris ṣalaye pe eniyan mejila lo ku ninu ijamba naa.

Eeyan mẹsan n'iroyin kọkọ gbe pe wọn ku lẹyin ti ijamba naa ṣẹlẹ, ṣugbọn dokita Idris ṣalaye pe awọn mẹwa lo ku gbara ti iṣẹlẹ ọ̀hún ṣẹlẹ, ti awọn meji si papoda nile iwosan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, ijọba Ipinlẹ Eko ti kede pe ki ẹnikẹni to ba fura pe awọn ẹbi wọn wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina naa kàn si ile-iṣẹ ijọba to n ri si ayẹwo DNA ati iwadii.

Ile-iṣẹ naa wa ni opopona Broad Street, to dojukọ ile itawe ni agbegbe CMS, ni Erekusu ilu Eko.