Ìpànìyàn: Ilé aṣòfin fẹ́ yí ìwé òfin lórí ọlọ́pàá ìpínlẹ̀

Bukola Saraki àti Ike Ekweremadu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn sẹ́nẹ́tọ̀ ń wá ojútùú sí ìpànìyàn l'orílẹ́èdè Nàìjírìa

Ile Asofin Agba l'Abuja ti bẹrẹ ilana lati ṣe ayipada iwe ofin orilẹede Naijiria ko le faye gba dida ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ati awujọ silẹ.

Aarẹ ile Bukola Saraki lo sọrọ naa di mimọ lori opo Twitter rẹ lẹyin ipade ile lọjọ Iṣẹgun.

Igbesẹ yii ni ṣe pẹlu ero ile lati wa ojutu\u si iṣẹlẹ ipaniyan to gbode kan l'orilẹede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀàrẹ Buhari ti gba Ààrẹ Macron ti orílẹ̀èdè France lálejò nilu Abuja

Ile Asofin Agba tun pinnu pe awọn awọn yoo b'ọwọ lu aba lori atunṣe ile iṣẹ ọlọpaa laarin ọṣẹ meji.

Ọpọ lo ti n da labaa wipe ọlọpaa ipinlẹ lo le dẹkun ipaniyan ni Naijiria, ṣugbọn ijọba apapọ ko ti fọwọ si.