Ìdìbò Ekiti: Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú òṣiṣẹ́ méjì l'Ekiti lórí PVC

DSS Image copyright Beeg Eagle
Àkọlé àwòrán DSS wọ ileewe Ekiti

Ikọ ọlọpàá ọtẹlẹmuye (DSS) ti mu awọn ọsiṣẹ meji ni ileewe girama musulumi Ola Oluwa to wa ni Ado-Ekiti, ni Ipinlẹ Ekiti lori ẹsun pe wọn gba awọn kaadi idibo silẹ lọwọ awọn olukọ yooku.

Awọn ọṣiṣẹ meji ti wọn mu naa jẹ akọwe Ọga agba ileewe naa ati oṣiṣe kan to jẹ oluranlọwọ ni ọfiisi naa.

Ọga agba naa, ọgbẹni Sunmọnu Olaoye ni awọn olukọ naa n ṣe ẹda (photocopy) kaadi idibo wọn ni lori ẹrọ to wa ni ọfiisi oun, ati pe kii ṣe pe wọn n da awọn kaadi naa jọ.

O ni oun ko mọ igba ti ṣiṣeẹda kaadi ara ẹni wa di ẹsẹ ti awọn DSS yoo maa le awọn olukọ kaakiri fun.

Iroyin sọ pe ikọ DSS naa digun de ileewe naa pẹlu aṣọ dudu ati iboju, ti wọn si fi tipatipa mu awọn oṣiṣẹ naa lọ.