Ọbasanjọ: Mo leè fi Atiku yangàn pé yóò sisẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀

Yakubu Dogara, Bukola Saraki, Goodluck Jonathan, ati Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Àkọlé àwòrán,

Atiku Abubakar ló ń díje sípò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlù PDP l'ọ́dún 2019

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ti kede faraye pe ori oun wu nipa Abubakar Atiku tii se igbakeji oun tẹlẹ, ti oun si lee fi yangan nibikibi, se ti ọmọ ẹni ba dara, o yẹ ka wi.

Ọbasanjọ fọwọ idaniloju yii sọya nibi ayẹyẹ wiwe l;awani oye fun oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar gẹgẹ bii Waziri ti Adamawa.

Ninu ọrọ rẹ, Ọbasanjọ fikun pe, Atiku to ni agbega lati ori oye Turaki Adamawa si Waziri Adamawa yii, ko ni ja igbimọ Emir Adamawa to yan sipo kulẹ, to fi mọ ati awọn ọmọ Naijiria lapapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

"Mo fi da yin loju pe Atiku yoo sisẹ gẹgẹ bii Waziri pẹlu ọwọ, apọnle ati ẹyẹ, ti ori gbogbo yin yoo si wu nipa rẹ.

Awọn eeyan jankan-jankan lati ilẹ yii ati loke okun lo peju sibi ayẹy iwe lawani oye naa.

Atiku Abubakar di Waziri Adamawa lọ́jọ́ ìbí rẹ̀

Bí Alhaji Atiku Abubakar ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọjọ Aiku, naa ni wọn wee ni lawani oye Waziri ti ilu Adamawa.

Lara awọn to peju, pesẹ si ibi ayẹye ọhun ni a ti ri aarẹ Naijiria nigba kan Oloye Olusegun Obasanjo, ọmọwe Goodluck Jonathan, aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Bukola Sarakin ati olori ile aọsfin kekere, Yakubu Dogara ati awọn eekan awujọ.

Atiku ninu ọrọ to fi sori ikanni Twitter sọ pe, oun ko ni gbagbe iwe lawani naa laipẹ.

Oniruuru ikini lo ti n waye fun bayii.

Oniruuru ikini ku oriire orikadun ni o ti wọle fun oludije si ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria, Atiku Abubakar bi o ti ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni ọjọ aiku.

A bi Atiku Abubakar ni ọjọ kọrundinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 1946 ni ilu Jada ni ipinlẹ Adamawa.

Aarẹ ile aṣofin apapọ, Bukọla Saraki, olori ile aṣoju-aṣofin Yakubu Dogara atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa ni wọn ti n kii ku oriire.

Ninu ọrọ rẹ, eyi to fi sita lori ikanni Twitter, Dogara ṣapejuwe Atiku gẹgẹ bii awokọṣe fun ọpọ awọn ewe ati ọdọ paapaa awọn ti wọn n gbaradi gẹgẹ bii olori lẹka gbogbo.

"Eekan eto iṣejọba tiwantiwa ni o jẹ, o si ti pese anfani lọpọlọpọ fun awọn ọdọ nipa idasilẹ awọn ileewe, ileeṣẹ kereje-kereje atawọn ohun meremere miran lorilẹede Naijiria."

Ninu ọrọ tirẹ, sẹnetọ Ben Murray Bruce ni ọmọ Naijiria ti o ti san ọjọ fun orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ ọna ni Atiku.

Bi ikini yii ṣe n lọ naa ni ọbalaye ipinlẹ ilu Yola, Alhaji Muhammadu Aliyu Barkindo Mustapha tun ṣe fi jẹ Waziri ti Adamawa.

Atiku si ni yoo jẹ Ẹni keje ti yoo maa jẹ oye yii.

Atiku, Secondus léwájú èèkàn PDP lọ̀ ìpolongo Ekiti

Àkọlé àwòrán,

Agogo meji abọ ọsan ni eto naa, to yẹ ko ti bẹrẹ ni agogo mẹwa, to bẹrẹ.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri, Atiku Abubakar lo lewaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu lọ sibi aṣekagba ipolongo idibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP fun idibo gomina nipinlẹ Ekiti.

Aṣekagba ipolongo ibo naa waye ni agbegbe Ojumose roundabout ni ilu Ado-Ekiti ni Ọjọbọ pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa kaakiri ibu at'oro orilẹede Naijiria ni ikalẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Atiku Abubakar ni irinajo irapada awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni ojuṣe ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbe dani bayii atipe gbogbo ogo ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria janfani rẹ labẹ iṣejọba PDP ni wọn yoo da pada.

Àkọlé àwòrán,

Ọjọgbọn Olusola Kolapo Eleka ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP

"PDP yoo pada lọna to lapẹrẹ. Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ko gbọdọ faye gba itanjẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ẹgbẹ oṣelu PDP yoo da iṣọkan orilẹede Naijiria pada bi o ba ti pada si ori iṣejọba"

Agogo meji abọ ọsan ni eto naa, to yẹ ko ti bẹrẹ ni agogo mẹwa, to bẹrẹ.

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo ayika ibudo ipolongo naa lo kun fun ero ti lilọ bibọ ọkọ si ti di iṣoro pẹlu.

Awọn to lorukọ lẹgbẹ oṣelu PDP bii, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus, gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Otunba Gbenga Daniel, alaga igbimọ afunṣọ ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Ahmed Markafi, gomina ipinlẹ Niger, Babangida Aliyu, gomina Ben Ayade ti i pinlẹ Cross River, gomina Ifeanyi Okowa olola ti ipinlẹ Delta ati gomina Ayọdele Fayoṣe ti o n gbalejo gbogbo wọn gan, ni wọn ti peju-pesẹ sibi ipolongo naa.

Bi gbogbo eyi ti n lọ naa ni awọn gbajugbaja olori takasufe, 9ice ati Taye currency naa n fi orin gbe wọn lẹsẹ nibi eto naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn to lorukọ lẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti peju-pesẹ sibi eto aṣekagba ipolongo PDP fun idibo gomina nilu Adfo Ekiti

Gbogbo ayika ibudo ipolongo naa lo kun fun ero, ti lilọ bibọ ọkọ si ti di iṣoro pẹlu.

Ọjọgbọn Olusola Kolapo Eleka ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP nibi eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti to n bọ ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keje, ọdun 2018.