Ekiti Election: Ǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Kayọde Fayẹmi

Fayẹmi ati Buhari Image copyright @kfayemi
Àkọlé àwòrán O jẹ minista fun ìwakùsà ati irin tutu laarin 2016 si 2018 labẹ iṣakoso Aarẹ Buhari

John Olukayọde Fayẹmi to dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni ajọ INEC kede gẹgẹ bi gomina tuntun fun ipinlẹ Ekiti.

  • A bi Ọmọwe John Olukayọde ọmọ Fayẹmi lọjọ kẹsan an, oṣu kejì, ọdun 1965 ni Iṣan- Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ Ekiti nipinlẹ Ekiti.
  • O lọ sile iwe Christs'School ni Ado Ekiti to jẹ olu ilu ipinlẹ Ekiti lọdun 1975 si 1980.
  • O kẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu Ìtàn ati Ọ̀na ibaṣepọ agbaye ni Fasiti Eko ati ti Ifẹ (OAU).
  • O gba oye ọmọwe ninu ẹkọ nipa Ogun ni King's College ti fasiti London nilu Ọba.

Ìwádìí BBC: Àwọn ará Èkìtì ń sáré gba N4,000 sáájú ìbò

Àwòrán ìbò Èkìtì lọ́dún 2014 fún àwòkọ́gbọ́n

  • John ọmọ Fayẹmi sin ilẹ Naijiria ilẹ baba rẹ̀ gẹgẹ bii olukọni ni Police College to wa niokoto lapa ariwa Naijiria.
  • O ṣiṣẹ olukọni to n ṣabẹwo ni ẹka ikọni nipa iṣelu àti ibudo ikọni nipa Aáwọ̀ píparí ni Fasiti ọgba ẹranko ti sánmọ́ntì gbé dunlẹ̀ ni Ibadan.
  • Bakan naa lo pẹ̀ka ìkọ́ni rẹ lọ ṣiṣẹ olukọni alábẹ̀wò lori ikọni nipa eto aabo nibudo ilẹ Adulawọ ni fasiti National Defense University, USA.
Image copyright Kayọde Fayẹmi/Facebook
Àkọlé àwòrán Ìgbà kejì nìyíì tí Fayẹmi yóò jẹ gómìnà l'Ekiti
  • O jẹ olugbani nimọran pataki fun igbimọ Oputa Panel ti Olusẹgun Ọbasanjọ gbe kalẹ lọdun 1999 lati sewadi awọn iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju to waye ni Naijiria laarin ọdun 1966 si 1999.
  • O ti ṣiṣẹ pẹlu àwọn ile iṣẹ bii Africa Research and information Bureau ni London laarin 1991 si 1993; Deptford City Challeng, ni London lọdun 1993 si 1995; minista fun ìwakùsà ati irin tutu lọdun 2016 si 2018 nigba to kọwe fipo rẹ silẹ ko le dije fun ipo gomina Ekiti.
  • O ti ṣe gomina ipinlẹ Ekiti ri laarin Ọjọ kẹrindinlogun, osu kẹwaa, ọdun 2010 si ọjọ kẹẹdogun, osu kẹwaa, ọdun 2014.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Kọmísánà fétò ìdìbò ní jàǹdùkú já àpótí gbà ní wọ́ọ́dù mẹ́fà