Ekiti Election: Ǹkan méwàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Oluṣọla Eleka

Ọ̀jọgbọn Eleka Oluṣọla Image copyright @elekaolusola
Àkọlé àwòrán Ọọlọ pipe ati ọgbọn iwe naa wa lara amuyẹ ipò olori

Oluṣọla Eleka tó ń díje fún ipò gómìnà Ekiti lábẹ́ asia ẹgbẹ́ oṣelu PDP.

  • Pa. Joshua Olusola Eleka ati Eunice Ademolabi Ojo Eleka bi Ọjọgbọn Klap Olubunmi Oluola lọdun 1968 ni Ikẹrẹ-Ekiti nipinlẹ Ekiti.
  • O lọ sile iwe St. Matthew's Primary School, Ikere-Ekiti (1972-1978) ati Annunciation School, Ikere-Ekiti (1978-1983).
  • Lati kekere lo ti n gba ẹbun ọmọ to yege titi to fi gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu ẹkọ ile kikọ ni Fasiti olódòdó ti Obafemi Awolowo (1989), ikeji ni Fasiti Eko (1993) ati ọmọwe ni OAU lọdun 2005.
Image copyright @solaeleeka
Àkọlé àwòrán A ju ara wa lọ, ìjàkadì kọ́ lọrọ ìdìbò Ekiti maa n jẹ́
  • O ṣiṣẹ olukọni ninu imọ ijinle nipa ile kikọ ni Fasiti OAU ki wọn to yan an nigbakeji Gomina Ayodele Fayose lọdun 2014.
  • O jẹ oluṣọagutan pẹlu ijọ Christ Apostolic Church nibi to ti jẹ ọkan lara awọn igbimọ alakoso wọn.
  • O jẹ alaga ẹgbẹ awọn kọlekọle nipinlẹ Ọṣun ldun 2006 si 2009 ati alakoso NIOB ni 2007 si 2009.
Image copyright @pdp
Àkọlé àwòrán Ọkan lara ẹgbẹ oṣelu Naijiria
  • Ojọgbọn Oluṣọla lo n ṣamojuto eto ẹkọ ipinlẹ Ekiti labẹ Fayoṣe, eyi to mu idagbasoke ba àṣeyọri awọn akẹkọọ loriṣiiriṣi Ekiti lọdun 2016.
  • O ti gba ami ẹyẹ pupọ nile, ati loke okun bii ti: Ami ẹyẹ Adari rere ni fasiti Pittsburgh USA, ami idanimọ fun iṣẹ rere ti fasiti Stanford University, America; ami ẹyẹ ògo lẹnu iṣẹ akanṣe ẹni ni fasiti Pittsburgh, America.
  • O gbe Diakoni Janet Oluṣọla niyawo.
  • Igbeyawo wọn ni èso ọmọ mẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Pọpọ sinsin idibo n lọ lori lawọn wọọdi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọ̀dé George: Ìpànìyàn ló yẹ ká dẹ́kun, ká tó máa du ààrẹ