Ekiti Election: Ǹkan mẹ́wàà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ṣẹgun Adewale

Segun Adewale Image copyright @segunaeroland
Àkọlé àwòrán Eyi wù mi kò wù ọ, ni yoo jẹ ki ará Ekiti yan ẹni tọkan onikaluku ba fẹ sípò

Ṣẹgun Adewale, olùdíje fún ipò gómìnà l'Ekiti lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú ADP

  • Ọ̀gbẹ́ni Michael Adewale ati Abilekọ Micheal Adewale ti agboole Aremọ bi Ṣẹgun Adewale lọjọ kẹẹdogun, oṣu karun un, ọdun 1966.
  • O lọ sile iwe Seventh-day Adventist School, Abule Oja, ipinlẹ Eko (1972 si 1978); o pari iwe girama rẹ ni Oriwu College, Ikorodu lọdun 1983 o si gba oye keji nipa iṣakoso gbogboogbo ni Fasiti ipinlẹ Eko (1995).
  • Ọdún 2012 si 2013 lo kẹkọ to tun gba iwe aṣẹ lati maa fo loke pẹlu Institute of Flight Operations and Dispatcher (IFOD), Texas ni America.
Image copyright @actiondemocraticparty
Àkọlé àwòrán Iru ẹgbẹ ti eeyan wa ninu eto oṣelu ṣe pataki lasiko yii
  • Otunba Ṣẹgun Adewale ni alaga ile iṣẹ Aeroland Group Companies.
  • O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party lọdun 2007.
  • O dije fun ipo aṣojuṣofin lọdun 2011 ati ti Sẹnetọ lọdun 2015.
  • Ọpọ èèyan lo maa n pe e ni Oṣaprapra nitori iwa ati ìṣe rẹ.
  • Die lara awọn ami ẹyẹ rẹ̀ ni: BRITISH AIRWAYS: Best Travel Agency Awards lọdun 2005/6,VIRGIN ATLANTIC: Best Partner Award (2005),BRITSH AIRWAYS: Platinum Agent Award (2004/5),QATAR AIRWAYS: special travel partner award (2007/8) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Image copyright @segunaeroland
Àkọlé àwòrán Ẹni to ba to gbangba sùn lọyẹ ni n dije fun ipò oṣelu
  • Otunba Adewale gbe Abilekọ Victoria Adewale niyawo.
  • Wọn bi ọmọ meji: Tosin ati Tobilọba Adewale.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ará Èkìtì ń fẹ́ gómìnà tí yòò tù wọ́n lára
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionItan Omi Erin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọ̀dé George: Ìpànìyàn ló yẹ ká dẹ́kun, ká tó máa du ààrẹ
Àkọlé àwòrán Awọn oludije gomina l‘Ekiti