'Àkójópọ̀ olóṣèlú kìí ṣe fún ànfàní Nàìjíríà'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

CUPP: JJ Ọmọjuwa sọ ohun tí ìdàpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí yóò jẹ́

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ji lánàá láti gbọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó tó ogójì yóò fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party lati yan ẹnikan ti yóò dupò ààrẹ ní ọdún 2019.

rAPC, SDP, pẹ̀lú àwọn èèkan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tókù ná wọn parapọ̀ ti wo pè ni Coalition of United Political Party.

Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé ti àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú máa ń darapọ̀, súgbọn kìí ṣe fún ìtẹ̀síwájú Nàìjíríà

Èyí jẹ́ àríwísí Kayode Ogundamisi àti JJ Omojuwa.

Kini awọn ọmọ Nàìjíríà ń rò pé ọjẹ́ ìlọsíwájú fún ìdìbò ọdún 2019?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kíló fa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn olósèlú yìí

Ẹgbẹ oselu Reformed All Progressive Congress, (R-APC), Peoples Democratic Party, (PDP) ati ẹgbẹ oselu mejilelọgbọn miran ti parapọ lati da ẹgbẹ oselu UPP silẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Kola Ọlọgbọndiyan nínú àlàyé rẹ̀ pẹ̀lú BBC sàlàyé pé àbájade ìpàdé ọjọ́ ajé ni pe ẹgbẹ oselu SDP ti Oloye Ou Falaye soju fun ati rAPC ti Alhaji Baraji soju fun pẹlu gbajugbaja oloselu ni, Dino Melaye ti gba lati sisẹ sowọpọ lati yan Aarẹ labẹ oselu tuntun naa lọdun 2019.

Awọn èèkàn nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń lọ bíi ogoji, lo darapọ̀ mọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.