#EkitiDecides: Wọn gbe Fayoṣe digba digba wọ inu ọkọ alaarẹ

Fayose pẹlu kọla lọrun
Àkọlé àwòrán Fayose ní àwọn oṣiṣẹ aláàbò n dun koko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa.

''Wọn fẹ dá emi mi lé gbodo"

Ìgbé ti Gómìnà Fayoṣe fi bọ ẹnu rèé níbi tó ti n ba àwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú PDP sọrọ níbi ìpolongo itagbangba ní ilé ìjọba Ekiti.

Fidio bi wọn se gbe Fayose lọ sile iwosan si lo wa nisalẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWọn gbe Fayose wọ ọkọ alaarẹ

''Wọn fẹ dá emi mi lé gbodo"

Ìgbé ti Gómìnà Fayoṣe fi bọ ẹnu rèé níbi tó ti n ba àwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú PDP sọrọ níbi ìpolongo itagbangba ní ilé ìjọba Ekiti.

Pẹlú bandeji lọrùn rẹ, ni Gómìnà Fayoṣe fi n bẹnu àtẹ lù bí àwọn òṣìṣẹ́ alaabó ṣe gẹgun tii lọrun nilé ìjọba, ti wọn sì yín afẹfẹ tajutaju lù u.

Bákannáà ló ní àwọn oṣiṣẹ aláàbò n dun koko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa.

Image copyright @OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Ìdìbò gómìnà nipinlẹ Ekiti yóò wáyé lọ́wọ́ Àbámẹ́ta

Fayoṣe figbe ta pé wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí òun

Akoroyin wa to wa ni ibì ìpolongo náà so pé, lẹyìn tí Fayoṣe bá àwọn akọròyìn sọrọ ní won gbé dìgbà dìgbà sínú ọkọ alarẹ lọ sí ilé ìwòsan.

Saaju la ti mu iroyin wa pe, oríṣiríṣi ìṣẹlẹ ló n sẹlẹ ni Ekiti, bi ọjọ idibo Gomina ti se n sunmo .

Lowuro Ọjooru, lẹgbẹ oselu PDP fi awọran Fayose sí ojú òpó Twitter rẹ pe, awon olópàá yín afẹfẹ tajutaju lù u.

Sugbọn iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe, awọn ọlọpaa duro wamu-wamu ni iwaju Ile Ijọba ipinlẹ naa bayi.

Akọroyin BBC Yoruba fidi rẹ mulẹ pe apere afefe tajutaju wa ninu afefe sugbon ko le fidi re mule boya won yin lu Gomina Fayose.

Nigba ti a kan si ile ise olopaa nipinle Ekiti, DSP Caleb Ikechukwu so pe isẹ aabo ilu lawọn n se ati wipe ko si nnkan to jo mo esun ti ẹgbẹ oseelu PDP fi kan wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ìjọba tó lọ ti yá owó kọjá agbára ìpínlẹ̀'

Sugbon awọn egbe oseelu PPD ni igbesẹ naa tumọ si idojukọ fun Gomina Ipinlẹ Ekiti Ayo Fayoṣe.

Wọn ni awọn ko ni gba ki ẹnikẹni dunkoko mọ awọn ni ọnakọna.

Bakaanna ni Gomina Ayo Fayose ti saaju sọ lori opo Twitter rẹ pe awọn ọlọpaa n yinbọn niwaju ile iṣẹ ijọba Ekiti.

O sọ pe ipinu awọn ọlọpaa naa ni lati ri wipe ẹgbẹ oṣelu PDP koni le ṣe iwọde ti wọn fẹ ṣe loni.

Awa ko mo nipa ohun ton sele

Agbẹnuso fẹ́gbẹ́ APC nipinle Ekiti, Ogbeni Taiwo Olatunbosun ninu iforowanilenuwo pẹlu ile ise BBC so pe, awọn ko lowo si ohun to sele.

Ọlatunbọsun ni "Alafia ni a wa ni olu ile ise egbe wa, ti a si n ba ise wa lo ni iroworose."

O so wi pe ''ti janduku ba wa ni igboro, a ko le tori pe a fe dibo ki olopaa wa ma wo wọn ni iran''