Adájọ́ dá ọdún ẹ̀wọ̀n loríṣìí fáwọn agbésùmọ̀mí Boko Haram

Abubakar Shekau Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram mẹ́tàléláàdọ́ọ́fà ti dèrò ẹ̀wọ̀n

Ile-ẹjọ to n ri si igbẹjọ awọn agbesumọmi ti dajọ ẹwọn fun ọmọ ẹgbẹ Boko Haram 113 lori ẹsun ifẹmi-eeyan-ṣofo.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram naa ni ijọba Apapọ kọkọ ṣe afihan wọn ni Barake Wawa ni ilu Kainji, nipinlẹ Niger.

Wọn fi oriṣiriṣi ẹsun to ni i ṣe pẹlu wiwa ninu ẹgbẹ agbusumọmi Boko Haram, ṣiṣe iranwọ fun Boko haram ati kikopa ninu pipa ọpọlọpọ alaiṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn onífàyàwọ́ ń lo Whatsapp láti ta heroin

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: 'Ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ń ṣẹlẹ̀ kìí ṣe ti òṣèlú'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn

Lara wọn ni Kabiru Mohammed lati ipinlẹ Katsina ti ile-ẹjọ dajọ ẹwọn ọgbọn ọdun pẹlu iṣẹ aṣekara fun.

Mohammed sọ pe oun jẹbi gbogbo ẹsun meje ti wọn fi kan an.

Ẹlomiran ni Adamu Mohammed lati ipinlẹ Gombe, ẹwọn ọdun mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni oun fi gbara lẹyin ti o jẹwọ pe oun fi ibọn pa eeyan mẹfa.

Ile-ẹjọ dajọ ẹwọn ogun ọdun fun Banzana Yusuf lati ipinlẹ Kano lori ẹsun wi pe o ṣe agbatẹru bi wọn ṣe ji awọn akẹkọbinrin Chibok gbe.