INEC: Àhesọ ni pé Abuja la ti máa kéde èsì ìdìbò Ekiti.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ekiti Election: Àhesọ ni pé Abuja la ti máa kéde èsì ìbò Ekiti

Ileese INEC
Àkọlé àwòrán Ẹ̀ka bánkì àpapọ̀ tó wà ní ìlú Ado-Ekiti ní wọ́n ti n pín àwọn ohun èlò ìdìbò nàá

Àjọ INEC ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn ohun èlò káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún tó wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti, ní ìgbáradì fún ìdìbò gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Àkọlé àwòrán Kọmiṣọna fun ajọ INEC nipinlẹ Ekiti ni INEC ṣetan láti fẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ kan ẹnikẹ́ni to ba n sọ ohun tójú rẹ̀ kò tó nípa ìdìbò Ekiti.

Ọjọgbọn Abdulganiy Raji to jẹ́ kọmiṣọna fun ajọ eleto ìdìbò INEC nipinlẹ Ekiti ni INEC ṣetan láti fẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ kan ẹnikẹ́ni to ba n sọ ohun tójú rẹ̀ kò tó nípa ìdìbò Ekiti.

Àkọlé àwòrán Gbágbáàgbá ni àwọn òṣìṣẹ́ ètò àábò dúró ní ibi tí wan ti n pín òhun èlò ìdìbà nàá

Raji ni INEC atawọn agbofinro pẹlu awọn oloṣelu ti fẹnuko lati rii pe ètò ìdìbò Ekiti yọri si rere.

Ìgbáradì INEC fún Ekiti

Raji gbà pé ìrírí kọja ẹgbẹ́ abewú fún INEC nitori pe àwọn ti ṣeto idibo ọgọsan lẹyin ti 2015 ti ko si wahala.

O ni INEC ti ṣatunṣe si ẹ̀rọ kaadi idibo ki kọnu-n-kọhọ kankan ma lè ṣẹlẹ nidibo gomina ipinlẹ Ekiti to máa waye lọjọ Abamẹta to m bọ yii.

Raji ni 913, 000 àwọn eniyan lo forukọ silẹ ti o lé diẹ ni 580, 000 sì ti gba kaadi idibo to ku bii 300,000 ti wọn kò tii gba kaadi idibo.

INEC gba pe wọn yoo ṣaṣeyọri idibo Ekiti gégé bi wọn ṣe ṣe ni Ibarapa (ipinlẹ Ọyọ), Anambra àti Ọṣun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: