Ekiti Election: Bọ́mọ kò bá bá ìtàn ó di dandan kó bá àrọ́bá

Ero n to
Àkọlé àwòrán Àwọn ènìyàn Ekiti ti ṣetan

Àwọn ènìyàn Ekiti yóò pààrọ̀ Fayooṣe sí gómìnà míì lónìí

Ọjọ́ kìnní, oṣù kẹwaa, ọdún 1996 nijọba Nàìjíríà dá ipinlẹ Ekiti pẹlu ipinlẹ marun un miran silẹ lábẹ ijọba ologun Sani Abacha. Ipinlẹ Ondo lo bí ipinlẹ Ekiti. O ni ijọba ibilẹ mẹrindinlogun nínú eyi ti eto idibo yoo ti waye kaakiri lonii.

Ọ̀pọ́ àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ń bèrè ìdí abájọ ti ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti fí yàtọ̀ sí àwọn ìdìbò tó kú.

Ní ti Ekiti, ìjà tó tẹ̀lẹ̀ ètò ìdìbò April 14 ọdún 2007 lo fi di ọrọ ile ẹjọ́ tó ń ri si awuyewuye tó súyọ lẹ́yìn ìdìbò, (Tribunal).

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (INEC) ka èsì ìbò pé Oní ìmọ̀ ẹrọ Segun Oni ló jáwe olúbori, tí Ọ̀mọ̀wé Kayode Fayemi sì fáriga pé òun ló jáwé olúbori, èyí ló fàá ti ọ̀rọ̀ fí di ti ilé ẹjọ́ sùgbọ́n tó fìdí rẹmi bọ̀ níbẹ̀.

Ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn tun ibo naa di kile ẹjọ to gbe e fun Fayẹmi.

Àkọlé àwòrán Ní ti Ekiti, ààwọ ẹni tó jáwé olúbori ló di èro ile ẹjọ́ tó ń ri si awuyewuye tó súyọ lẹ́yìn ìdìbò, (Tribunal) Lẹ́yìn àbájáde ìdìbò April 14 ọdún 2007.

Ètò ìdìbò yìí f'ọdun 2018

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oludije lo ti jade lati dije fun ipò gomina ipinlẹ Ekiti lọdun yii. Diẹ lara wọn ni:

ORÚKỌ ÀWỌN OLÙDÍJE ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ TÍ WỌ́N Ń DÍJE LÁBẸ́ RẸ̀
Kọlapọ Olusola Eleka Peoples Democratic Party (PDP)
John Olukayode Fayemi All Progressives Congress. (APC)
Ayodeji Lawrence Ayodele All Progressive Grand Alliance (APGA)
Sikiru Lawal Tae Labour Party (LP)
Abiodun Aluko Accord Party. (AP)
Babatunde Henry Afe Abundant Nigeria Renewal Party (ANRP)
Segun Adewale Action Democratic Party (ADP)
Orubuloye Dele Lucas All Grassroots Alliance Party (AGA)
Tosin Ajibare Independent Democrats Party (ID)
Olajumoke Saheed Democratic Alternative (DA)
Temitope Omotayo Young Progressives Party (YPP)
Tope Adebayo Advanced Peoples Democratic Alliance (APDA)
Akinloye Ayegbusi Social Democratic Party. (SDP)
Saheed Olawale Jimoh African Peoples Alliance (APA)

Ṣáájú ìdìbò 2018

Oriṣiiriṣi nkan lọ ṣẹlẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to n dije fun ipo gomina Ekiti paapaa àwọn ti PDP ati APC.

Àkọlé àwòrán Awọn oludije gomina l‘Ekiti

Bii Àwòrán ìbò Èkìtì lọ́dún 2014 fún àwòkọ́gbọ́n ti o dabi ibẹrẹ iṣẹle Fayoṣe ati Fayẹmi, 'Fayẹmi ṣì ní ẹ́jọ́ láti jẹ́ ní Ékìtì' ọpọlọpọ awuyewuye lo ti waye laarin awọn ẹgbẹ oselu mejeeji eyi ti Aarẹ Buhari fi wa si Ekiti fun ipolongo alaafia pe ‘Àláfíà ọmọ Naijiria lo jẹ mí logun'.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Sẹgun Adewale ní ìpèsè ohun ìdẹ̀rùn yóò bá ìfẹ́ aráàlú mu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Idibo ti bẹrẹ ni pẹrẹwu!

Ọpọlọpọ nkan lo ṣẹlẹ ni eyi ti Fayoṣe figbe ta pé wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí òun lẹyin to dara nibi ipolongo ko to di ero ile iwosan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Pọpọ sinsin idibo n lọ lori lawọn wọọdi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn

Eyi lo tun mu PDP sèwọ́de tako ìwà ipá l‘Èkìtì ni eyi to tun bi ero pe Fayoṣe yin Ngige fún bó se polongo ìbò fún PDP

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ìjọba ìbílẹ̀ làwọn òsìsẹ́ Inec yóó sùn mọ́jú ọjọ́ ìbò

Ọlọ́pàá 30,000 ní yóò mójútó ìdìbo Ekiti Bayii opolopo igbese nijoba atawon agbofinro ti gbe ki eto idibo Ekiti le jẹ aṣeyọri Wo ibi tí ìgbáradì fún ìbò gómìnà l'Ékìtì dé dúró

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Àwọn ohun èèlò ìdìbò ń dé síjọba ìbílẹ̀

Ajọ eleto idibo INEC naa sọrọ lori iṣẹ ti wọn ti ṣe de idibo Ekiti pe:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: 'Ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ń ṣẹlẹ̀ kìí ṣe ti òṣèlú'

Bi àwọn kan ṣe n yin Fayose ni awọn mii gba pe ọgbọn lo n da pe Fayose kọ́ ni olóṣèlú tí yóò kọ́kọ́ kán l'ọ́rùn'

Bayii àwọn eniyan Ekiti n fẹ alaafia, wọn de n fẹ jade dibo fun ẹni to wu wọn loni

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ará Èkìtì ń fẹ́ gómìnà tí yòò tù wọ́n lára