Yankari Reserve: Erin pa ènìyàn méjì ní ìlú Bajama

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ní erin náà lọ sí Gwartanbali níbi ti àwọn ará ìlú ti pé bòó tí wọn si ń ya fọto pẹ̀lú rẹ̀.
Ọmọ ọdún mẹ́sàn kan àti bàbá Ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ní Erin ti pa ní abújé Bajama tó sún mọ́ Yankari Reserve àti ti Safari lẹ́yìn tí wọn pejọ lati wòran erin àti láti ya fótò.
Alakoso igbo ti wọn ko àwọn eranko ìgbẹ́ sí yìí, Habu Mamman, lo fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde tó fi léde fún àwọn akọ̀ròyìn ní Bauch lónìí.
O ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni ọjọ́ kẹ́jọ oṣù yìí nígbà ti àwọn erin náà jáde kúrò nínú ọ̀gbà ní àárọ̀ tó sì mórílé ìlú Bajama.
O ní erin náà lọ sí Gwartanbali níbi ti àwọn ará ìlú ti pé bòó tí wọn si ń ya fọto pẹ̀lú rẹ̀.
Lójiji ni erin náà bẹ́rẹ̀ sí ni sìwàwù tó si ń lé ara ìlú lásìkò yìí tẹ ọmọkunrin kekere kan, Fa'izu Chiroma Musa pa, tó sì kú lójú ẹsẹ̀, síbẹ̀ àwọn ènìyàn náà kò dẹ̀yìn lẹ́yìn erin náà.
Ẹnìkejì, Haruna Abubakar, rí ikú tirẹ̀ he nígbà tí ó súnmọ́ erin náà láti ya foto, ti ọkan nínú wọn si ta nípàá, èyí ló ṣe okùfà ikú rẹ̀ ní dédé ààgo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́
Ólóri òun ni aláṣẹ Yankari ló ti ló kí àwọn ẹbí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀lẹ̀ sí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ekiti Election: Ará Èkìtì ń fẹ́ gómìnà tí yòò tù wọ́n lára
#EkitiDecides: Fayose sùn lórí ibùsùn aláìsàn