Ekiti Election: INEC gbé èsì ìdìbò Ekiti síta lẹ́kùnrẹ́rẹ́

esi idbo
Àkọlé àwòrán,

Abajade èsì idibo Ekiti gangan niyi

Èyí ni àbájáde èsì ìdìbò Ekiti láti ọ̀dọ̀ INEC gangan.

Ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ekiti ti kede pe awọn ti n ka ahesọ ọrọ kan to gba awọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye kan, nibiti wọn ti n kede esi ibo gomina ni ipinlẹ Ekiti lọna ti ko bofin mu.

Atẹjade kan ti Kọmisana fajọ eleto idibo nipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji fi sita nirọlẹ ọjọ Abamẹta, ni eyi ti jẹyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Kọmísánà fétò ìdìbò ní jàǹdùkú já àpótí gbà ní wọ́ọ́dù mẹ́fà

Atẹjade naa wa n fi to awọn ara ilu leti pe, ajọ eleto idibo si n ka awọn esi ibo naa lọwọ, bẹẹ si ni akojọpọ esi ibo si n lọ lọwọ lawọn ibudo akojọpọ esi ibo kan.

Àkọlé àwòrán,

Inec wa n rọ awọn araalu lati kẹyin si ayederu esi ibo to gba oju opo ayelujara kan.

"A wa n rọ awọn araalu lati kẹyin si ayederu esi ibo to gba oju opo ayelujara kan."

Bayii, ajọ eleto idibo INEC ti kede esi idbo naa ni eyi ti Kayode Fayemi ti egbe oselu APC ti jawe olubori.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Decides: Abiọdun Aluko ní báwọn se kàwé tó l‘Ekiti, ìyà sì ń jẹ àwọn