Ekiti Election: EFCC ní ilé ẹjọ́ nìkan lo lé sọ ohun tí yóò dé bá Fayoṣe

Ayọdele Fayose Image copyright @Fayose
Àkọlé àwòrán Ofin Naijiria ko faaye gba gbigbe awọn to wa nipo iṣakoso lọ sile ẹjọ lasiko ti wọn ba wa n'ipo.

Ajọ EFCC ti fesi lori ikede kan to fi sita lori Twitter nipa Gomina Ayọdele Fayose.

EFCC ni ikede ori Twitter naa ki i ṣe ipinnu ajọ naa.

Ninu ikede kan ti ajọ naa fi sita l'oju opo Facebook rẹ̀ lo ti sọ pe ajọ naa ta kété si oṣelu, ti ko si ko ipa kankan ninu idibo to waye laipẹ nipinlẹ Ekiti.

Ati pe ko si ìdí kankan fun un lati dunnu lori laasigbo to deba oludije kankan, tabi baba-isalẹ fun oloṣelu.

EFCC ni bo tilẹ jẹ wipe lootọ ni ẹsun iwa ọdaran n bẹ l'ọ́rùn Fayose, o ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ̀ to wa nilu ado-Ekiti nikan lo le sọ boya igbẹjọ yoo wa lori ẹ̀sùn naa, ti Fayose ba pari saa rẹ gẹgẹ bi gomina Ekiti.

EFCC pa ìkéde Twitter rẹ́ nípa Fayoṣe

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ nidi eto ọrọ aje ati inawo, ni Naijiria, EFCC, ti pa ikede kan to fi sita lori Twitter lọjọ isinmi pe 'awọn ti gbọn awọn iwe to wa lọwọ awọn lori magomago to waye lori awọn ile adiyẹ ti wọn dá sílẹ̀ l'Ekiti.'

Image copyright EFCC/Fayose/Twitter
Àkọlé àwòrán Ẹ̀nu kun EFCC lórí ìkéde tó fi síta nípa Fayose níkété tí wọ́n kéde èsì ìbò gómìnà Ekiti

EFCC sọ ninu ikede naa pe 'pọpọṣinṣin ti tan...' eyi to mu ki awọn eeyan maa woye pe o seese ki wọn fẹ bẹrẹ si ni tanna wadi Gomina Ayọdele Fayose to da awọn ile adiyẹ naa silẹ nigba to fi kọkọ ṣe gomina l'Ekiti.

Ko pẹ ti ajọ INEC kede esi ibo to waye ni ipinlẹ Ekiti lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ninu eyi ti igbakeji Fayose, Olusọla Ẹlẹka, to dije fun ẹgbẹ oṣelu wọn, PDP, ti fidi rẹmi, ni ajọ EFCC fi ikede naa sita.

Won ni ki Gomina ipinlẹ Ekiti wa ṣalaye bó ṣe na owó iṣẹ́ àkànṣe Integrated Poultry Project / Biological Concepts Limited l'Ekiti.

Eyi fihan pe gbogbo agbara koṣeemu ti Fayoṣe ni lori aleefa gẹge bii gomina ipinlẹ Ekiti labẹ ofin Naijiria a too pari.

Ajọ EFCC fi soju opó twitter wọn pe inawo ti pari bayii l'Ekiti ki Fayoṣe wa sọ bo ṣe na owo to le ni biliọnu kan Naira, 1.3Trillion.

Oṣu kẹwa, 2018 ni saa Fayose yoo pari gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ekiti, ti Kayọde Fayẹmi ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan yoo si gba iṣẹ.

Bi awuyewuye yii ṣe n lọ lọwọ ni olugbani nimọran Aarẹ Muhammadu Buhari, Lauretta Onochie fi tikẹẹti ọkọ ofurufu kan to ni orukọ gomina Fayose sita.

Ofin ìmúnitì to wa ninu iwe ofin orilẹede Naijiria n daabo bo awọn to wa nipo iṣakoso ni Naijiria, eyi ti ko faaye gba gbigbe wọn lọ sile ẹjọ lasiko ti wọn ba wa n'ipo.

Laipẹ yii ni ile ẹjọ fi gomina nigba kan ri fun ipinlẹ Taraba ati Plateau si ẹwọn lori ẹsun iwa ibajẹ ti ajọ EFCC fi kan wọn pe wọn na owo ilu ninakuna nigba ti wọn fi wa nipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: