Ekiti Election: Alailójúti ní Buhari- Fayose

Ayọdele Fayoṣe ti máa ń tako ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari
Àkọlé àwòrán,

Ayọdele Fayoṣe ti máa ń tako ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari

Irọ́ ni Buhari ń pa, kò féran ìdàgbàsókè ìṣèjọba alágbádá rárá

Láti ọjọ ti wọn ti ká èsì ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ekìtì ní gbogbo ọmọ Nàìjíríà tí ń retí kí Gomina Ekìtì, Ayodele Fayose fèsì lórí àbájáde èsì ìdìbò gomina ipinlẹ Ekiti.

Sùgbọ́n o, nínú ọ̀rọ̀ tí Fayose fi ránṣẹ́ fun ìgbà àkọ́kọ́ lórí ẹ̀rọ̀ ìkànsíraẹni twitter rẹ̀ ló ti sọ pé aláìlójútì, afipá gbà ìjọ̀ba ní ààrẹ Muhammadu Buhari.

O ní ó ṣe ni láànú pé Buhari tún ń fí tayọ̀tayọ̀ lo ọlọ́pàá, ọmọogun àti àwọn agbófinro miran láti maa yìnbọn ní bùdó ìdìbò tí wọn si ji àwọn àpóti ìdìbò gbé lọ

Ó fẹ́sùn kan Buhari pé kìí ṣe àdrí tó bòwọ̀ fun ìjọba àwa-arawa rárá

Níbo ni Fayose wa:

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń bèrè pé níbo ni Gómìnà Ayọdele Fayoṣe wà láti ìgbà tí wọ́n ti kéde èsì ìdìbò náà ní ọjọ́ àìkú.

Kayode Fayemi ni ó pegedé nínú ìdìbò náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fi ìbò 197,459 ju olùdíje ẹgbẹ́ PDP, Oluṣọla Ẹlẹka tó ní ìbò 178,121 lọ.

Àwọn ìròyìn kọ̀ọ̀kan sọ wí pé ó ti kúrò nílùú lọ sí ilẹ̀ Faranse sugbọn àwọn kan sọ wí pé ó ṣì wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Bí èyí ṣe ń lọ, ọ̀kan lára àwọn olùgbaninímọ̀ràn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Lauretta Onochie fi àwòràn ìwè morajà tí Fayoṣe fi sanwó láti tẹkọ̀ òfurufú létí lọ sí ilẹ̀ Faranse síta lórí Twitter.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

Fayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀ ní kété tó di gómìnà Ekiti

Ẹwẹ̀, akọ̀ròyìn wa tó wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti ti ń wá ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà àti agbẹnusọ rẹ̀ sùgbọ́n pàbò ló já sí.

Ó ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́nu wí pé kò tíì sọ ohunkóhun nípa èsì ìbò náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé igbákejì rẹ̀ tó jẹ́ olùdíje ti jáde láti kọ̀ èsì tí àjọ INEC gbé jáde.

Lọ́gán tí wọ́n kéde èsì ìbò náà ni ajọ̀ EFCC ti sọ wí pé wọn yóò bẹ̀rẹ̀ títọpinpin Ayo Fayoṣe lórí bó ṣe na owó iṣẹ́ àkànṣe Integrated Poultry Project / Biological Concepts Limited to yé ko lo fun iṣe akanṣe l'Ekiti.

Sùgbọ́n lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ta ko àjọ EFCC pé wọ́n ń gbè lẹ́yìn ẹnìkan ni EFCC ti yọ àtẹ̀jáde náà kúrò lóri Twitter wọn.

Ayodele Fayoṣe kò ṣì lórí wíwá ọ̀rọ̀ láti sọ sí ohunkóhun ti Ààrẹ Muhammadu Buhari bá sọ.