Ìfipábánilòpọ̀: ọlọ́pàá ní àáfà aríran yóò jìyà ẹ̀sẹ̀ rẹ̀

Chike Godwin Oti
Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko sọ pé àáfà tó fipá bá akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lòpọ̀ ní ìlú Ikorodu jẹ́wọ́ pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn náà

Ile-iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe Aafa aríran Mustapha Hammed to fipa ba akẹkọbinrin Ile-Ekọ giga olukọni agba ni Akoka, Eko lo pọ yoo jiya ẹṣẹ rẹ.

Agbẹnusọ fun Ile-iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko Chike Godwin Oti to ba BBC Yoruba sọrọ fidi rẹ mulẹ pe gbogbo eto ti to lati gbe Aafa naa lọsi ile-ejọ bayii.

Ọgbẹni Oti ṣalaye pe Alfa Hammed to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun lo riran si akẹkọọbinrin naa wipe yo jade laye laarin wakati mẹrinlelogun ti ko ba ṣe etutu lati yẹ iku kuro lori ara rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi ọrọ awọn ọlọpaa, akẹkọbinrin naa gba aafa gbọ, o si tẹle e lọ si Ilu Ikorodu nibi ti o ti fi ipa ba a lo pọ.

Igbesẹ naa lo jẹ ki ọkan akẹkọọ naa poruru papaa julọ bi awọn ẹbi rẹ ti sọ pe aafa fẹ fi ọmọ awọn ti ko ti i mọ ọkunrin ri ṣe oogun owo ni.

Agbẹnusọ fun Ile-iṣẹ Ọlọpaa fi kun ọrọ pe awọn ọlọpaa ko le sọ boya otitọ ni pe aafa naa fi asọ nun oju-ara ọmọbinrin naa lẹyin ti o ba lopọ gẹgẹ bi awọn ẹbi rẹ ṣe sọ ati pe wundia ni ọmọ awọn.

O tẹsiwaju pe lori awuyewuye to n lọ lode pe ọmọbinrin naa n gbo bi aja, oun ko le sọ boya ootọ ni tabi irọ.

Ṣugbọn o ṣalaye pe ile-ẹjọ ni yoo dajọ to yẹ fun Aafa ariran Hammed lẹyin ti ọrọ naa ti de ile-ẹjọ bayii.