APC Ọ̀sun: Wọn kò sàlàyé ìdí tí ọjọ́ ìbò abẹ́nú náà fi yípadà

APC

Ẹgbẹ oṣelu APC ni Ipinlẹ Oṣun ti kede ọjọ Ẹtì, ogunjọ, oṣu Keje, gẹgẹ bi ọjọ idibo abẹle lati yan aṣoju ẹgbẹ naa ninu ibo gomina to n bọ.

Ṣaaju ni ẹgbẹ naa yẹ idibo ọhun to yẹ ko waye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, fun idi kan ti wọn ko ṣalaye.

Alakalẹ̀ eto idibo naa wa lara idi ti o jọ pe, wọn fi sun idibo naa siwaju, nitoripe wọn fẹ ki Yari ṣe ipade pẹlu awọn oludije mẹtadinlogun to n kopa ninu idibo abẹle naa.

Akọwe iponlongo ẹgbẹ APC, Mallam Bolaji Abdullahi to kede ọjọ tuntun naa ni, igbimọ alamojuto fun idibo abẹle naa, ti gomina ipinlẹ Zamfara, Abdul'aziz Yari n dari, yoo ṣe ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ l'Ọjọ́bọ̀, nilu Oṣogbo, to j olu ilu ipinl Ọṣun.