'Àwa ọ̀dọ́ Nàìjíríà kìí ṣe ọ̀lẹ rárá'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Star Boy: Mo ti rọ́ lẹ́sẹ̀ àti lọ́wọ́ rí lẹ́nu wíwa BMX

Ṣíṣe eré ìdárayá 'Skating' àti 'BMX' kẹ̀kẹ́ wíwà kò ni jẹ́ ki ọ̀dọ́ hùwà kiwà ní Nàìjíríà mọ́.

Mathew Temitope ti àpèjá rẹ̀ ń jẹ́ Star Boy ba BBC Yoruba sọrọ lori àyájọ́ 'Go Skate àti BMX Day' ti wọn ṣe ni Lekki nipinlẹ Eko.

O mẹnuba pataki ki àwọn ọ̀dọ́ niṣẹ ti wọn n ṣe ati níní ìfẹ́ si ere idaraya ti wọn ba yàn laayo ki wọn le di akọṣẹmọṣẹ ninu ere idaraya naa lọjọ ọ̀la.

Mathew maa n wa kẹ̀kẹ́ BMX daadaa, o ni ere idaraya mejeeji yii kìí ṣe fún ọ̀dọ́ to ba ya ọ̀lẹ rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mathew Temitope mẹnuba awọn ijamba to rọ̀ mọ́ ṣiṣe eré idaraya Skating ati wiwa kẹ̀kẹ́ BMX.