Ibrahim Coomasie ni ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní ọdún 1993 sí 1999

Ibrahim Coomasie
Àkọlé àwòrán,

Ibrahim Coomasie jẹ olori ileeṣẹ ọlọpàá Nigeria laarin 1993 si 1999

Ọ̀ga àgbà ọlọ́pàá nígbà kan rí, Ibrahim Coomasie, ti faye sílẹ léni ọdun mẹrindinlọgọrin.

Oloogbe naa to jẹ ọmọ Ipinlẹ Katsina jẹ olori ileeṣẹ ọlọpàá Nigeria laarin 1993 si 1999.

Coomasie naa lo tun jẹ ẹgbẹ igbimọ agbaagba oke ọya, Arewa Consultative Forum.

Ọdun to kọja ni iroyin jade pe Coomasie bọ lọwọ awọn agbenipa to ya bo ile rẹ ni Katsina.

Ọdun 2014 ni wọn yan gẹgẹbii olori ACF.