Osun 2018: Àwọn aráàlú da ìbéèrè bo àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Ọṣun
Osun 2018: Àwọn olùdíje ADC, ADP, APC, SDP bá aráàlú sọ̀rọ̀ lórí èròǹgbà wọn
Kọntínúítì, gbèsè, fásitì Lautech àti àwọn ìbéèrè mìíràn lo jẹyọ ní ìpàdé ìtagbangba Ọṣun
Ipade itagbangba ti ile ise iroyin BBC Yoruba se fun awọn oludije sipo Gomina nipinlẹ Osun ti waye.
Oludije mẹrin lo yoju sibi ipade naa ti won si dahun awọn ibeere orisirisi to fi mọ ibeere lori bi won yoo ti se se eto ijọba ti wọn ba de ori oye.
Àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùba ní ìpínlẹ̀ Ọṣun
Lara awọn to kopa ni Alhaji Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ oselu APC, Alhaji Fatai Akinbade ADC,Iyiola Omisore SDP ati Alhaji Moshood Adeoti ADP
Alhaji Adeoti
Alhaji Gboyega Oyetola ni gbese daa
Bí atọ́kùn ṣe ń tọ́kùn ètò náà dáradára ni àwọn ènìyàn ń gbádùn ètò náà nílé àti lórí àwọn ìtàkùn àgbáyé BBC Yorùbá tí wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ àti ìbéèrè tiwọn náà ránṣẹ́.
Àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùba ní ìpínlẹ̀ Ọṣun
Akinbade: ''Due Process'' ni awa yoo fi se ijọba
Awọn ọdọ se pataki fun isejoba wa
Àwọn Olùdíje sípò gómìnà l'Osun naa tun se fọ̀rọ̀wérọ̀ lórí àlàkalẹ̀ ètò tí wọ́n ní fún ará ìlù ati nnkan miiran.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ́ Kẹjìlélógún, Osú Kẹ̀sán an, Ọdún 2018 ni ìdìbò sí ipò gómínà yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun.
Ajọ Eleto Idibo ni orilẹ-ede Naijiria, INEC, ti kede orukọ awọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Oṣun, igbakeji wọn ati ẹgbẹ oselu wọn.
Ọjọ Kejilelogun, Osu kẹsan an, ọdun 2018 ni idibo si ipo gomina yoo waye kaakiri ipinlẹ Osun.
Idibo ti yoo waye naa yoo ni awọn oludije mejidinlaadọta pẹlu orukọ ẹgbẹ oselu wọn ni ori patako Ajọ INEC to wa ni ilu Osogbo ni ipinlẹ Osun.
Ademola adeleke lo n dije du ipo labẹ ẹgbẹ oselu PDP nigba ti Adegboyega Isiaka Oyetola yoo dije labẹ ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC).
Bakan naa, Iyiola Omisoore n jade lati ẹgbẹ oselu Social Democratic Party (SDP), nigba ti Fatai Akinade Akinbade, yoo ma di je du ipo labẹ ẹgbẹ oselu African Democratic Congress (ADC).
Idibo Osun: Yusuf Lasun ní wọn ń dìtẹ̀ mọ òun nínú ẹgbẹ́ APC
Oríṣun àwòrán, @Lasun4Governor
Ìgbákejì olori ilé ìgbimọ aṣojú-sòfin, Ọgbẹ́ni Yusuf Lasun ní, òun kò ṣetán láti fí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) sílẹ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, òun fìdí rẹmi nínú ìdìbò àbẹlé ẹgbẹ́ lati dupò gómìnà tó wáyé nílu Oṣogbo lóṣù keje ọdun 2018.
Lasun fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn àkoròyìn sọ̀rọ̀ lọjọ Aiku ńlùú Oṣogbo, to si tun fọwọ sọya pe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ dìtẹ̀ mọ òun nínú ìdìbò abẹ́lẹ́ náà, sibẹ ẹgbẹ́ APC náà ní òun yóò bá dé èbúté ògò.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Mo ṣì ń péjú níbi ìpàdé ẹgbẹ́, èmi àti àwọn olólùfẹ́ mi kò pinnu láti fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ yálà nísinsìn yìí tàbí lọ́jọ́ iwájú".
'À ó sa ipá wa láti gbárùkù ti ẹgbẹ́ lásìkò ìdìbò tí yóò wáyé lójọ́ kejìlélogún, oṣù kẹsan an, nítori pé ó ti dandan pé, nínú ìdìbó tẹnikan bá gbégbá orókè, kí ẹnikan fìdí rẹmi.Igbakeji olori ile aṣojuṣofin, Họnọrabu Lasun Yusuff ni ko daju pe ẹgbẹ oṣelu APC lee kogoja ninu idibo pataki gbogbo to n bọ lọna.Họnọrabu Lasun Yusuff ni ohun to lee ko ẹgbẹ oṣelu APC yọ naa ni ki àwọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa o pe aro ati ọdọfin wọn jọ lati pari gbogbo ariyanjiyan ti n bẹ láàárín agbo wọn." Bi o tilẹ jẹ pe ahesọ ọrọ n lọ kaakiri pe mo fẹ fi ẹgbẹ silẹ, irọ ni.
Lotọ, awọn kan gbimọ abosi lodi si mi lasiko idibo komẹsẹ̀-o-yọọ́ fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn emi ko lee tori eyi ṣiṣẹ tako ẹgbẹ tabi fi ẹgbẹ oṣelu yii silẹ"
Onídájọ́ Fọlahanmi Oloyede léwájú ìwọ́de òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì fún ọjọ́ mẹ́ta l'Ọ́ṣun
Yusuf Lasun jẹ́ ọkan nínú àwọn akópa mẹ́tàdínlógún tó dìde láti gbégba ipò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípìnlẹ̀ Ọsun lóṣù kede ọdun 2018.
Idibo Osun: Gboyega Oyetola pegede ninu ìdìbò abẹ́nú APC ní Osun
Ogbeni Gboyega Oyetola lo jawe olubori ninu idibo abẹlẹ ti ẹgbẹ oselu APC, ni igbaradi fun idibo gomina ti yoo waye ni Osu Kẹsan an, ọdun 2018.
Seneto Ovie Ọmọ Agege lo kede esi idibo naa nilu Osogbo.
Oyetola to je olori awọn osisẹ ni ọfiisi Gomina Aregbesọla lo pegede pẹlu ibo 127,017 láti fi ẹ̀yìn ìgbà kejì olórí ile asofin kékeré l'Abuja Lasun Yusuf tó ní 21,975 àti àwọn Olùdíjé mìíràn na le lẹ̀.
Lara awọn to wa nibi ikede esi idibo naa ni Gomina ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola, Gomina ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi ati Gomina ipinlẹ Zamfara, Abdul'aziz Abubakar Yari to tun jẹ Alaga eto idibo abẹlẹ ohun.
Oríṣun àwòrán, XXX
Rauf Aregbesola yoo fi ipọ gomina si le leyin ọdun mẹjọ labẹ ẹgbẹ oselu APC
Abdul'aziz Abubakar Yari sọ wi pe idibo abẹlẹ naa se afihan bi idibo gbogboogbo yoo ti se lọ ni ọdun 2019.
Àwọn èèyàn àti awakọ̀ ké igbe ìrora bí àwọn ọkọ̀ ńlá ṣe dí ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Apapa-Oshodi pa
Òwúrọ̀ ọjọ́ ìdìbò náà ni àwọn olùdíje mẹ́ta, Moshood Adeoti, Peter Babalọla àti Senatọ Babajide Ọmọworarẹ sọ pé àwọn kò dìje mọ́ ninu awọn eniyàn mẹtadinlogun ló n dije láti gbé àsìá ẹgbẹ APC sókè bíi olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun.