NSC: Ìjọba àpapọ̀ fẹ kọ́ ibùdó ìgbọ́kọ̀sí fáwọn táńkà eponí Enugu

NSC: Ìjọba àpapọ̀ fẹ kọ́ ibùdó ìgbọ́kọ̀sí fáwọn táńkà eponí Enugu

Fidio to wa loke yii lo n sọ ewu to wa ninu bawọn ọkọ agbepo nlaa-nla se maa n da wahala silẹ nilu Eko atiisoro tawn ara ilu n koju.

Eyi si lo mu ki isẹlẹ di ailasọ lọrun paaka, to wa di ohun apero fawọn ọmọ eriwo bayii.

Lọwọ-lọwọ bayii, Ìjọba àpapọ̀ tí kede pé, láìpẹ́ yìí ní àwọn yóò bẹ́rẹ̀ kíkọ́ ibudo igbọkọsi fún àwọn ọkọ̀ àjàgbé tó n gbé epo oní mílíọ̀nù mẹ́jọ lé díẹ̀ dọ́là, lọ sí ìlú Ogbulafor, ìpínlẹ̀ Enugu.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọkọ̀ ńlá dí ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Apapa-Oshodi pa

Ọ̀rọ̀ náà wáyé nípa àkitiyan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń rí si kíkọ ẹrù wolé láti òkè òkun (Nigeria Shippers Council), lásìkò ti akọwé ẹgbẹ́ náà, Hassan Bello, n gbàlejò ajọ to n rí sí ètò amáyédẹrun nílù Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ni, iṣẹ́ àkànṣe ọhún yóò pèsè iṣẹ́ fún ènìyàn tó lé ni ẹgbẹ̀rún mẹ́tà nígbà tó bá parí.

Wọn ní ìjọba ìpínlẹ̀ Enugu ti pèsè ilẹ̀ éékà mẹ́rìndílogun fún àkànṣe iṣẹ́ náà, tí àwọn sí ń reti àwọn àgbáṣe ti yóò wá forúkọ sílẹ̀ lati ṣe iṣẹ́ náà, tí ẹni to ba yege yóò sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Iṣẹ́ náà yóò pari láàrin ọdún mẹ́jì láti fún àwọn ọkọ agbepo tó ń dá wàhálà sílẹ̀ nílù Eko yìí, ní ànfàni láti ní ibomiràn ti wọn yoo máà kó ọkọ̀ sí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti ń ké gbàjarè pé, ìdíwọ́ àti ìjàmbá ti àwọn ọkọ̀ ǹlá yìí ń se fún ìlú èkó ti pòjú pàápàá jùlọ níti ètò ọ̀rọ̀ ajé àti àwọn ẹ̀mi tó ń sòfò

'Ẹ̀mí ń bọ́ lójú ọ̀nà Apapa-Oshodi ní Eko'

Awọn awako nla ati awọn eeyan to n fẹsẹ rin ni wọn ti kepe ijọba lati tun ọna mọrosẹ Apapa-Oshodi ṣe, lẹyin ti ọna naa ti di pa ti awọn ọkọ si n sun, ti wọn n fa.

Awọn eeyan ati awakọ ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ni wọn pẹnu pọ sọ pe ọna to bajẹ ni o n fa sunkẹre-fakẹrẹ lopopona ọhun.