Atiku Abubakar: A ó rántí Ààrẹ Buhari fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ lásìkò rẹ̀

PDP mega rally Image copyright Twitter/@Atiku
Àkọlé àwòrán Igbákèjì Ààrẹ̀ ilẹ̀ Naijiria tẹ́lẹ̀rí, Atiku Abubakar yóò dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP ní 2019.

Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar ti sọ wi pe awọn eniyan ko ni gbagbe isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari nitori ọgọọrọ itajẹsilẹ to waye lasiko isejọba rẹ.

Atiku sọ eyi nibi ipolongo gbogboogbo to ti se afihan ipinnu rẹ ni ilu Adamawa ni Yola, lati dije du ipo Aarẹ ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye niọdun 2019.

Oludije naa to buẹnu atẹ lu isekupani ọlọgọọrọ to n waye ni awọn agbeegbe kan lorilẹede Naijiria, fi ẹsun kan isejọba Buhari wi pe ọpọ eniyan lo ku ni asiko rẹ.

Image copyright Twitter/@Atiku
Àkọlé àwòrán ‘A ó rántí Ààrẹ Buhari fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ lásìkò rẹ̀’
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSegun Ọdẹgbami: Mo kọ̀ láti lọ sí APC àti PDP nítorí ń kò fẹ́ ní ‘Bàbá ìsàlẹ̀’

Amọ, ọpọ eniyan lo ti fi ẹsun kan igbakeji aarẹ tẹlẹri naa lori ẹsun iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu ni awujọ.