Ìjàmbá ọkọ̀ Mínísítà: Ogún èèyàn míì tó sèse ń gba ìtọ́jú

Ogún èèyàn míì tó sèse ń gba ìtọ́jú

Awọn ọkọ to fara gba ijamba Image copyright @rasebby
Àkọlé àwòrán Ogún èèyàn míì tó sèse ń gba ìtọ́jú

Ori lo ko minisita fere idaraya lorilẹ-ede Naijiria, Solomon Dalung yọ nigba ti awakọ ọkọ pijo 406 kan sadede rari wọ ara awọn ọkọ to to tẹle ni ọwọọwọ nilu Gombe.

Iroyin naa ni papakọ ofurufu ni awọn ẹsọ ati awọn amugbalẹgbẹ ti lọ pade minisita naa, igba ti wọn si n kọja laarin ilu ni isẹlẹ naa sẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osisẹ kan ni ileesẹ adani kan to wa fun ipese eto aabo nipinlẹ Gombe, Sunday Jika, toun naa wa ninu awọn ọkọ to kọwọ rin pẹlu minisita, ẹni to tun fidi isẹlẹ yii mulẹ fun ileesẹ akoroyin jọ ilẹ wa, ni ọkọ pijo naa gbinna, tawọn si ri eeyan mẹta yọ jade ninu rẹ, amọ o ni, o se ni laanu pe awakọ ọkọ Pijo naa jona mọ inu ọkọ ọhun.

Image copyright @TheEmirateNG
Àkọlé àwòrán Ìpínlẹ̀ Gombe ni ìjàmbá náà ti wáyé nígbà tí ọkọ̀ pijó 406 kan lọ rárí wọ ààrín àwọn ọkọ̀ tó tò tẹ̀lé mínísíta féré ìdárayá ní Nàíjíríà.

Jika fi kun pe o to ogun eeyan to wa ninu ọkọ bọọsi to tẹle minisita to fara gbọgbẹ, amọ ti wọn ti n gba itọju nile iwosan bayii.