Ìjàmbá Ọkọ̀: Àdúgbò Palmgrove ni ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Ojú ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Ikorodu Image copyright Twitter/Mhagayr
Àkọlé àwòrán Ìjàmbá Ọkọ̀ BRT gbẹ̀mí obìnrin kan l'Eko

Obinrin kan ti ṣagbako iku ojiji lẹyin ti ọkọ BRT gba ni agbagbe Palmgrove nilu Eko loni ọjọ Aje.

Ẹni kan ti isẹlẹ naa soju rẹ, Killian Obinna fidi rẹ mulẹ pe, obinrin naa fẹ sọda ọna mọrosẹ Ikorodu ni ọkọ BRT ọhun fi gba.

O fi kun ọrọ rẹ pe loju ẹsẹ ni ọmọbinrin naa jẹ Ọlọrun nipe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni aṣọ ni wọn fi yi oku obinrin naa, ti wọn si gbe si ẹgbẹ kan loju ọna