Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìpínlè Ekiti sọ̀rọ̀ owó t'ijọba jẹ wọ́n
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

NLC Ekiti: Ìròyìn èké ló gba orí ayélujára

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni ipinlẹ Ekiti, Ade Adesanmi ti sọ pe irọ funfun balau ni iroyin to n tan kalẹ kaakiri wipe, ẹgbẹ naa fun gomina Ayodele Fayose ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati san owo ti o jẹ wọn.

Adesanmi to ba BBC Yoruba sọrọ, sọ pe, atẹjade ayederu ni awọn eeyan n ka lori ẹrọ ayelujara.

O fi kun ọrọ rẹ pe, gbogbo ẹgbẹ oṣiṣẹ lapapọ ṣẹṣẹ fẹ ṣe ipade lori ọrọ naa ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adesanmi sọ pe, ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti nireti wipe, ijọba gomina Ayodele Fayose to n kogba nilẹ, yoo san gbogbo owo ti o jẹ awọn oṣiṣẹ, ko to lọ.