Ọ̀gá ọlọ̀pàá: Saraki gbọdọ̀ wá sọ àsọyé lórí lẹ́tà tó kọ

Ibrahim Idris ati Bukọla Saraki
Àkọlé àwòrán Idris ni o pọn dandan fun aarẹ ile asofin agba ilẹ wa naa lati wa yọju si ileesẹ ọlọpaa ni Abuja.

Ọga agba ọlọpaa ni orilẹ́-ede Naijiria, Ibrahim Idris ti tun ransẹ pe aarẹ ile asofin agba nilẹ wa, Bukọla Saraki lẹẹkan si, pe ko yọju si ẹka ọtẹlẹmuyẹ to wa nilu Abuja fun ifọrọwanilẹnuwo lori bi wọn se ro mọ isẹlẹ idigunjale to waye nilu Ọffa.

Ninu lẹta kan ti ọga agba ọlọpaa naa kọ si Saraki lo ti ni ko yọju lọjọ isẹgun ni deede aago mẹjọ aarọ, ko lee wa tanna si ibasepọ rẹ pẹlu awọn afurasi adigunjale marun-un to wa ni ahamọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

O fi kun pe nigba ti ileesẹ ọlọpaa ransẹ pe Saraki fun igb akọkọ, lẹta kan lo kọ ransẹ, to si sọ ninu rẹ pe oun ko ni anfaani si akọsilẹ ọrọ awọn afurasi ti wọn darukọ oun gẹgẹ bii ẹni to n pese irinsẹ fun awọn.

Idris ni idi ree to fi pọn dandan fun aarẹ ile asofin agba ilẹ wa naa lati wa yọju si ileesẹ ọlọpaa ni Abuja.