Codeine: Àjọ aṣọ́bodè gba ògùn ikọ́ N200m lọwọ awọn onífàyàwọ́

Image copyright Nigeria Customs Service
Àkọlé àwòrán Ọga agba ajọ aṣọbode ni iwọ oorun gusu Naijiria Muhammad Garba sọ pe awọn ara ilu lo ta wọn lolobo nipa oogun naa

Àjọ aṣọbode Nigeria ti já ogun ikọ olomi Codeine to owo rẹ to igba miliọnu naira gba ni Ijẹbu Ode, ni Ipinlẹ Ogun.

Ọga agba ajọ aṣọbode ni iwọ oorun gusu Naijiria Muhammad Garba sọ pe awọn ara ilu lo ta wọn lolobo nipa oogun naa ti awọn si lọ dabu awakọ naa ati ẹni to ni ọkọ naa.

O ni bii ẹẹdẹgbẹta pali ogun ikọ naa, ni awọn ja gba nigba ti wọ da ọkọ naa duro.

Ẹ ò ranti wipe ọrọ ogun ikọ olomi Codeine di ọrọ ti gbogbo awọn eniyan orilẹede Naijiria n da si nigba ti BBC gbe iwadii kan jade to ṣafihan bi ogun na sẹ n ṣọṣẹ lara awọn ọdọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò òògùn ikọ́ Codeine: Àpọ̀jù rẹ̀ ń ya ọ̀dọ́ ní wèrè