Linda Igwetu: Wọ́n sin àgùnbánirọ̀ t'ọ́lọ́pàá yìnbọn ni Anambra

Oku Linda Igwetu Image copyright @mosco4all/Twitter
Àkọlé àwòrán Agbole baba rẹ ni Ipinlẹ Anambra ni wọn sin si

Awọn ẹbi Linda Igwetu to jẹ agunbanirọ ti ọlọpaa pa to ku ọjọ kan ko pari isinru ilu rẹ ni Abuja ni ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun yii ti sin ọmọbirin naa ni Ipinlẹ Anambra.

Agbo ile Evidence Igwetu ni wọn sin si.

Ẹ o ranti ẹgbọn oloogbe naa, Chinenye ṣe ṣalaye fun BBC pe bii agogo mọkanla alẹ lọjọ naa lọun ni Linda pari iṣẹ ni Outsource Global Company Mabushi to n ba ṣiṣẹ ni ọjọ Iṣẹgun.

Lẹyin naa ni oun ati awọn alajọṣiṣẹ rẹ lọ sile igbafẹ kan lati lọ ṣe ajọyọ ipari ìsìnrú'lú eyi ti ayeye rẹ yẹ ko waye loni (Ọjọ́bọ̀) jakejade orilẹede Naijiria.

Image copyright Linda Igwetu/Facebook

Oju ọna ni ọlọpaa kan ti yinbọn si ọkọ wọn ti o si ṣeku pa Linda.