Mali: Ààrẹ ọmọ ọdún 73 ń wá ọdún márùn-ún síi gẹ́gẹ́ bí ààrẹ

Mali Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mali

Orílẹ̀èdè Mali yóò rọ́kẹ̀kẹ̀ lónìí gẹ́gẹ́ bí wọn yóò ṣe tú jáde lati lọ dìbò yan ààrẹ tí yóò máa tukọ̀ orílẹ̀èdè wọn.

Orílẹ̀èdè náà ti ń wá ọ̀nà làti f'òpin sí ìṣòro ṣégesège òṣèlú àti ọrọ̀ ajé tó ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Olùdíje mẹ́rìnlélógún ló ń díje fún àwọn ipò tó ga, tó fi mọ́ ààrẹ tó wà lórí àléfa báyìí Ibrahim Boubacar Keita, ẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin tó sì ńwá ọdún márùn-ún síi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ ọmọ ọdún 73 ń wá ọdún márùn-ún síi

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLẹ́yín ọpọ̀lọpọ̀ ọdún, Lagbaja da ìlù bolẹ̀ nílú Abuja

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ kan tó rọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Al-Qaeda ti dúnkoko láti dènà ìbò náà.

Akọ̀ròyìn BBC Tomi Ọladipọ jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba orílẹ̀èdè Mali ti kó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n òṣìṣẹ́ aláàbò jọ láti ríi pé àbò wà nìlùú lákokò ìdìbò kó má baà sí ìbẹ̀rù pé ìkọlù àwọn ẹ́gbẹ́ Jihad yìí.

Wọ́n ṣe èyí nítorí ó ṣeé ṣe kí lemọ́lemọ́ ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ti àwọn ẹlẹ̀sìn Islam sàkóbá fún ààrẹ Ibrahim Keita gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń fẹ́ kí wọ́n tún un yàn.

Ẹni tó máa ń ta kò ó jù ni adarí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Soumaila Cisse tó fi ẹ̀sùn kan ààrẹ pé kò mú àwọn ìlèrí tó ṣe ní ìdìbò tó kọjá ṣẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adari ẹgbẹ alatako

Ó ṣe pàtàkì pé ẹni tí yóò jáwé olúborí gbudọ̀ ní ju ìdajì gbogbo ìbò tí ìdìbò àkọ́kọ́ tàbí kí iye ìbò tirẹ̀ pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹkùn Ìlà Oòrùn Mali kò sí lábẹ́ àkóso ìjọba. Ọwọ́ ikọ̀ ilẹ̀ Faransé àti àjọ ìsọ́kan àgbáyé ni ojúṣe àbò ẹkùn náà wà.

Fún ìdí èyí, ìpolongo kò fibẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ níbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgbologbo ijapa l'aafin Sọun

Related Topics