Ọlọ́pàá Ondo: A ti da ọtẹlẹ̀múyẹ́ síta láti ṣe àwári Fagoriola.

Dele Fagoriola Image copyright Fagoriola/facebook
Àkọlé àwòrán Ìròyìn tó tẹ BBC lọ́wọ́ sọ pé Fagoriola jẹ́ alága ní Akure North láàrín 2004/2007 lábẹ́ Gómiànà Olusẹ́gun Agagu

Alága ijọba ìbílẹ̀ Aríwá Akure nígbà kan rí, ní ìpínlẹ̀ Ondo, Dele Fagoriola, tí di ẹni àwáti léyìn tí wọn tí jíi gbé nínú oko rẹ̀.

Ìròyìn tó tẹ BBC lọ́wọ́ sọ pé, Fagoriola jẹ́ alága ijọba ibilẹ Akure North láàrín ọdun 2004 si 2007, lábẹ́ Gómiànà Olusẹ́gun Agagu, sùgbọn wọn jíi gbé nínú oko rẹ̀ tó wà ní ààlà Ondo àti Ekiti láàrin Akure si Ikẹ̀rẹ́ lópòónà Ekiti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Busuyi, tó jẹ́ ọkan lára mọ̀lébi rẹ̀ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé, wọn jíi ẹ̀gbọ́n òun gbé ní dédé ààgò mẹ́ta osan pẹ́lù ẹgbọn rẹ̀, tí àwọn ajínigbé náà kò sì tíì bá ẹ̀bí sọ̀rọ̀ rárá lórí ohun tí wọn fẹ́ gbà.

Bákan náà, ọkan lára àwọn òṣìṣẹ́ Fagoriola tí ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ sàlàyé pé, ọ̀gá àwọn wá ṣe àbèwo iṣẹ́ tí àwọn ńṣe lọ́wọ́ nígbà ti àwọn agbébọn ọ̀hún dé láti jíi gbé.

O ní gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkurin náà ló fí àwọn boju pélù àwọn ohun ìja tó bani lẹ́ru.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, agbẹnusọ fún ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo, Femi Joseph sọ pé, àwọn ti da àwọn ọtẹlẹ̀múyẹ́ síta láti ṣe àwári Fagoriola.