Ortom yọ amúgbálẹ́gbẹ́ 28 nípò nínú àtúntò ìgbìmọ̀ ìṣèjọba

Gomina samuel Ortom

Oríṣun àwòrán, Samuel Ortom/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Laipẹ yii ni Samuel Ortom fi APC silẹ lọ PDP

Gomina ipinlẹ Benue ti yọ awọn amugbalẹgbẹ rẹ mẹtejidinlọgbọn kuro nipo.

Akọwe ijọba ipinlẹ naa, Tony ijoho to kede eyi rọ wọn lati ko awọn ohun elo ijọba to ba wa ni ikawọ wọn fun awọn akọwe agba ni ileeṣẹ ijọba wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìdìbò Ọṣun: Omisore, Akinbade ni ìjọba àpapọ̀ fẹ fi N10,000 rà'bò ni

Gẹgẹ bii agbekalẹ ikede naa ṣe sọ, mẹtadinlogun ninu wọn lo jẹ oluranlọwọ pataki fun gomina; ti mọkanla si jẹ oluranlọwọ agba fun gomina.

Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe gomina Ortom yọ awọn eeyan naa nipo lati lee fi aaye gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn padanu ipo wọn gẹgẹ bii ọmọ igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣelu naa lẹyin ti gomina Ortom darapọ to si gba iṣakoso igbimọ ẹgbẹ oṣelu PDP nibẹ.

Ni oṣu meji sẹyin ni Gomina Ortom fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Njẹ o ranti bi awọn aṣofin kan gbimọ ati yọ gomina Ortom nipo?

Àwọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mẹjọ ninu ọgbọn to wa ni Ipinlẹ Benue, ti fun Gomina Ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ni iwe pe awọn yoo yọ nipo lẹyin ọjọ meje si asiko yii.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ sọ pe, awọn aṣofin mẹjọ naa joko ni ọjọ aje nibi ti wọn ti gbe igbesẹ naa, ti awọn ọlọpaa ko si jẹ ki awọn asofin mejilelogun yoku wọ ile aṣofin, nigba ti ijoko naa n lọ lọwọ.

Osẹ to kọja ni ile igbimọ aṣofin naa ni ki awọn mejilelogun to ku lọ fidi mọle fun gba die.

Àkọlé fídíò,

Shomolu gbajúmọ̀ fún ìwé títẹ̀

Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹnusọ fun gomina Ortom, Terve Akase niidaji oorọ ọjọ aje lawọn ọlọpaa ya bo ilu Makurdi, tii se olu ipinlẹ naa, ti wọn si se atilẹyin fun awọn asofin mẹjọ pere ninu ọgbọn lati wọle joko sepade nile asofin ọhun, nigba ti wọn le awọn asofin mejilelogun yoku sẹyin lati wọle sile asofin naa.

Kin ni Ortom ri sọ si isẹlẹ yii ?

Akase fi kun pe gbedeke ọjọ meje pere ni awọn asofin mẹjọ ọhun fun gomina Ortom lati ko aasa rẹ kuro nipo, bi bẹẹkọ wọn ni awọn yoo yọ nipo.

gbẹnusọ fun gomina Ortom ni o da awọn loju pe ijọba apapọ lo n se atilẹyin fawọn asofin mẹjẹẹjọ naa lati ditẹ mọ gomina ipinlẹ Benue nitori bo se fi ẹgbẹ oselu APC silẹ laipẹ yii.

O fi kun pe olori ile asofin ipinlẹ Benue, ti wọn yọ nipo laipẹ yii lo lewaju awọn asofin meje yoku, to n se atilẹyin fun aarẹ Buhari lati wa gunle igbesẹ lati yọ gomina Ortom nipo.

Ẹ o ranti wipe ose to kọja naa ni Ortom pinnu pe, asiko ti to lati fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ PDP, lori ẹsun pe ijọba apapọ ko ka awọn ara Benue si.