Òwú tí ìyá gbọ̀n, lọmọ ó ran ni ọ̀rọ̀ Saraki nínú òṣèlú

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ilé tóó lọ: Bukola Saraki padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó ti wá sí APC

Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Sẹnetọ Bukola Saraki ti di adari ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin to kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP.

Akọwe Ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ọlọgbọndiyan, ṣalaye fun BBC Yoruba lasiko to n fidi ọrọ naa mu lẹ pe Bukola Saraki lo jẹ ẹni to gajulo pata ninu gbogbo awọn ti wọn dibo yan ninu ẹgbẹ Naa.

O ni fún idi eyi, Saraki ni ọga agba patapata lẹyin alaga gbogboogbo ẹgbẹ naa.

Ọlọgbọndiyan fesi si ọrọ ti Alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, iyen,Adams Oshiomole sọ wi pe ki Saraki fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Aarẹ ile aṣofin lẹyin to fi ẹgbẹ awọn silẹ.

O ni wi pe Oshiomole kò ni asẹ lati sọ pe ki Saraki fi ipo rẹ silẹ.

Akowe ipolongo ẹgbẹ oselu PDP naa fikun ọrọ rẹ pe awọn ti ṣetan lati mu igba daadaa pada wa fun awọn eniyan ni ọdun 2019, pẹlu ileri pe awọn ọdọ yoo laaye lati dije dupo fun Ile Igbimo Asofin labẹ asia PDP ninu idibo gbogboogbo to n bọ.

Ṣé ìwọ mọ Bukọla Saraki dáadáa?

Ọpọ eeyan la bi sile aye, sinu abule ati inu ẹbi kòlà-kòṣagbe, taa si lee pe wọn ni atapata dide. Amọ ti wọn fori ja igbo lati ri i pe wọn de ipo giga nile aye lai naani ọpọ ẹgun to wa ni ọna wọ̀n.

Sugbọn ni ti Abubakar Bukola Saraki, Ọmọbọlanle ni a ba maa pee, nitori pe o ba ọla nile ni, to si dide lati inu ọla lọ si ipo giga.

Bukọla Saraki fori sọlẹ sile aye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 1962, si idile oloogbe Olusola Saraki, ti oun naa jẹ agba oselu ati gbaju-gbaja ni awujọ wa.

Koda, oun ni Aarẹ Ile Aṣofin Agba orilẹ-ede Naijiria lọdun 1979 si 1983. Gbogbo eniyan lo si maa n pee ni ‘Baba Oloye’ gẹgẹ bii àpèjà rẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Ọlọpaa di ẹnu ọna ile Saraki pa

Eto ẹkọ ọmọ Baba Oloye kii e gbẹfẹ

Olusọla ko ginra rara lati fun arẹmọ-kunrin rẹ, Bukola ni awọn ohun mere-mere to n mu ki aye dun fun ọmọde, to si tun n pese ọmọ fun ipo giga ni ọjọ ọla, paapaa, ta a ba wo awọn irufẹ ile ẹkọ to ran Bukọla lọ.

Ile iwe Kings College ni ipinlẹ Eko ni Bukọla lọ feto ẹkọ girama lọdun 1973 si 1978, ile ẹkọ naa kìí ṣe f'awọn ọmọ kola-kosagbe ẹda, nitori ‘yapo-rẹ-wo’ ni nigba naa.

Niwọn igba to si jẹ́ pe ẹni nla, lo n ṣe ohun nla, lẹyin ile ẹkọ girama, Baba Oloye sọ ọmọ rẹ si ilu Ọba, nile ẹkọ Cheltenham College ni ilẹ Gẹeṣi ni ọdun 1979 si ọdun 1981 nibi to ti gba iwe ẹri girama miran.

Saraki kẹkọọ gboye ni Fasiti ilu London nibi ti o ti gba iwe ẹri gẹgẹ bii oniṣegun oyinbo lọdun 1982 si 1987.

Niwọn igba to jẹ pe idi isẹ ẹni, laa ti n mọ ni lọlẹ, Bukọla ṣiṣẹ ni ile iwosan Rush Green to wa ni Essex gẹgẹ bi oniṣegun oyinbo lọdun 1988 si 1989.

Amọ̀, nigba to ya, Bukọla di igba ati agbọn rẹ pada si ilẹ Naijiria, nitori ile ni abọ isinmi oko, to si di oludari ile ifowopamọ Société Générale (to ti kogba wọle bayii) laarin ọdun 1990 si 2000.

Gẹgẹ bi owe Yoruba to sọ pe, owu ti iya ba gbọn, naa ni ọmọ yoo ran, arẹmọ Baba Oloye dara pọ mọ baba rẹ ninu oselu, to si tẹsẹ bọ bata baba rẹ, ọmọ kii kuku ba ipele iya rẹ, ko ṣi aṣọ dá.

Ìgbà lonígbà ń kà ni Irinajo Saraki lagbo oselu Naijiria

Ni ọdun 2000, Saraki wọ agbo oṣelu orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti Aarẹ ana, Oluṣegun Obasanjo yan-an sipo gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki lori eto inawo.

Saraki di gomina ipinlẹ Kwara labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2003, lẹyin ti o koju ajagun-fẹhinti Mohammed Lawal ninu idibo gomina lọdun naa, to si fi ẹyin Lawal janlẹ siyalẹnu àwọn eniyan.

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Bukola Saraki ṣe gómìnà ìpinlẹ̀ Kwara fún ọdún mẹ́jọ

Lawal lo wa lori oye gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kwara nigba naa, pẹlu atilẹyin oloogbe Oloye Olusola Saraki to jẹ baba-isalẹ rẹ.

Ede aiyede to waye laarin Lawal ati baba rẹ lo ṣokunfa bi Bukọla ṣe rọwọ mu di gomina pẹlu atilẹyin Baba Oloye fun ọmọ rẹ.

Saraki lo saa meji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kwara, ti i ṣe ọdun mẹjọ. to si tun tẹsiwaju ninu oṣelu nigba ti o dije fun ipo sẹnẹtọ lati ṣoju aarin-gbungbun ipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Bukola Saraki rọ́pò abúrò rẹ̀ obìnrin Gbemisola Saraki-Forowa gẹ́gẹ́ bí sẹnẹtọ

O jawe olubori ninu ibo naa, o si rọpo aburo rẹ obinrin Gbemisola Saraki-Forowa ti o n ṣoju ẹkun naa tẹlẹ, lai naani atako baba rẹ, to n gbè lẹyin aburo rẹ lati di gomina ipinlẹ Kwara.

Isẹlẹ yii lo mu ki ogiri la ẹnu laarin baba ati ọmọ, sugbọn itakun to ni ki erin ma wọ odo ni iwa Bukọla ni agbo oselu, toun -terin ni yoo jọ lọ, eyi to fi idi rẹ mulẹ pe ko sẹni ti Biukọla ko le e gbéná woju lori ipo oselu to ba n fẹ ni akoko kan.

Lati ẹgbẹ oṣelu PDP ni Saraki ti kọkọ yapa lọ si APC ko too di aarẹ ile igbimọ aṣofin.

Lẹyin o rẹyin, Saraki fi ẹgbẹ PDP silẹ lọ dara pọ mọ APC pẹlu awọn sẹnẹtọ mẹwaa miran.

Ọpọ eeyan si lo gbagbọ pe o fi ẹgbẹ PDP silẹ nitori pe o fẹ di aarẹ ile igbimọ aṣofin Agba l'Abuja ni.

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Twitter

Àkọlé àwòrán,

ọ̀pọ̀ gbágba pé èrò ọkàn Bukola Saraki ni láti di Ààrẹ ilé aṣòfin Àgbà l'Abuja

A gbọ pe ẹgbẹ oṣelu APC fẹ yan Aarẹ ile igbimọ aṣofin Agba l'Abuja lati Ila-Oorun Ariwa orilẹ-ede naijiria.

Ikú ń dẹ dẹ̀dẹ̀; dẹ̀dẹ̀ na n dẹ ikú ni bi Bukọla Saraki ṣe di aarẹ ile asofin agba laarin atako to lagbara

Saraki to wa lati Aarin gbungbun Ariwa ja fun ominira fun awọn sẹnẹtọ lati yan olori fun ra wọn, lai gba asẹ lọwọ baba isalẹ kan-kan, o ja fun ipo aarẹ naa, to si bori, eleyi to muu di Aarẹ ile naa.

Ori ko ni oun yoo ba ọrun duro ni akoko ti Bukọla lo gẹgẹ bii aarẹ ile asofin agba, ọpọ ete, iditẹ-mọni, oniruuru ẹsun, atako ati igbẹjọ si lo la kọja.

Ara ko rọ okun, bẹẹ ni ko rọ adiẹ ni ibasepọ Saraki ati ijọba Muhammadu Buhari, ti ọpọ eeyan si mọ pe ilẹkẹ ma ja sile ma ja sita ni, ibi kan naa lo ma ja si ni awọn mejeeji jọ n se.

Kin lo mu Saraki dagbere fun APC, to si gba PDP lọ

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018 ni Saraki kede lori opo Twitter rẹ pe, oun ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si PDP to ti wa tẹlẹ.

Saraki fi kun ọrọ rẹ pe oun fi ẹgbẹ naa silẹ lẹyin ti oun ti ro o daadaa fun igba pipẹ.

O ni oun fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ nitori idojuti ati inuni-bini nla ti oun doju kọ ninu ẹgbẹ naa.

O sọ pe oun kuro ninu ẹgbẹ naa lati faaye gba alaafia ni.

Lakotan, a lee ni eeyan takun-takun, ti ọpọ̀ eeyan lee ri bii ‘Katapila’ ni Bukọla Saraki lagbo oselu Naijiria.

Kin ni ọjọ iwaju Saraki ni agbo oselu Naijiria

Niba yii to ti wa di ‘Ọmọwale’ ni PDP, kin ni yoo jẹ atunbọtan rẹ nibẹ?

N jẹ ipo rẹ bi aarẹ ile asofin agba ko ni mu u gbún ẹgbẹ oselu APC lẹẹkan sii?

Ṣe Saraki yoo tun jẹ lọ bi, ni agbo oselu Naijiria lẹẹkan sii, paapaa nibayi ti ẹnu n kun-un pe o fẹ du ipo aarẹ?

Bi o tilẹ jẹ pe ko tii si idahun sawọn ibeere naa bayii, sugbọn a mọ pe laipẹ ni idahun yoo maa ba awọn ibeere yii bi ọjọ ba se n gun ori ọjọ ni agbo oselu Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Lion Chaser: Richard, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún se iná tó ń lé kìnìún