Sex: Aṣà tó wọ́pọ̀ fún ìgbádùn ìbálopọ̀ lágbáyé

Pop Art illustration - Female lips and a speech bubble saying 'sex', comic book style Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ǹjẹ́ bákan náà ní ǹkan rí ní gbogbo àgbáyé?

Ìbalòpọ̀ jẹ́ ohun tó ti pẹ́ tí ọ̀pọ̀ sì máa ń se lágbàyé.

Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ọ̀ lọmọ́ sorí nípa bí àwọn ènìyàn ṣe n ṣe ìbálòpọ̀ láti orílẹ̀èdè kan sí omíràn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn ọ̀nà tí obìnrin fi le gbádùn ìbálòpọ̀

Emmerson Mnangagwa jáwé olúbori ní Zimbabwe

Láì déènà pẹnu lórí iṣẹ́ tí a gbudọ̀ mú ṣe, èto kan lórí BBC Crossing Continent tí fi ọ̀pọ̀ àkókò sínú ìwádìí láti mọ oriṣi ọna ìbálòpọ̀ lágbàyé.

Láti orí àwọn ti kò mọ obinrin sí àwọn tí wọn ń ní àjoṣepọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi obinrin, èyí ní oníruuru ọná tí àwọn ènìyàn fí má ń ni ìbálòpọ̀ jákèjádò àgbáyé.

1. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ẹkun gbùngùn kan ní Hawaii

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán N ó sọ orúkọ mí fún o tí ìwọ náà bá sọ tirẹ fún mi

Nínú àṣà, àwọn Hawaii wọn máa ń sin ojú ara, wọn a tún fún un ní orúkọ tìfẹ́tìfẹ́.

Sùgbọ́n kò tán síbẹ̀ àtolówó àtolòsì ló ni orúkọ àrà ọ̀tọ̀ tí wọn sọ ojú ara ìbálòpọ̀ wọn, èyí ti wọn ń pè ni 'mele ma'i'

Dókítà Milton Diamond, tó jẹ́ onímọ nínú ọnà ti àwọn ènìyàn Hawaii máa ńgba ní ìbálòpọ̀, sàpèjúwe bí Ayaba Lili'uokulani ki ojú ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èròjà ara tí ń ṣe "fìkìfakà sókèsódò"

Awọn ará Japan kìí fi bẹ́ẹ̀ ní ìbálòpọ̀ ní tiwọn

Image copyright Getty Images

Japan tún jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó tí fí àdíkù bá ọmọ bíbí.

Kì ṣe èyí nìkan: Rúbà ìdáàbò, òògun oníkóró, oyún ṣíṣí, jẹ́ ọ̀kan tí kò jẹ́ kí àìsan ìbálòpọ̀ wọ́pọ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán E kọọ

Lórílẹ̀-èdè Brazil Ẹja ní ọkúnrin máa ń fí wá ojú obínrin

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sọọ́ pẹ̀lú ẹja

Ní abúlé kan tí wọn ń pé ní Mehinaku, ní gbùngùn Brazil, àwọ obìnrin ibẹ̀ ti wá ọ̀nà àbáyọ láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn tó ńkọ ẹnu ìfẹ́ sí wọn.

Àwọn okunrin tó bá mọ ohun ti wọn ń ṣe yóò gbé ẹja wa nínú ìgò wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbaàrún pe ọdún kan