Nollywood: Àwọn obìnrin Yollywood tó ń tà wàrà-wàrà

Ayo Adesanya

Oríṣun àwòrán, ayoadesanya

Àkọlé àwòrán,

Ayo Adesanya

Ayo Adesanya

Ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 1969 ni wọ́n bí gbajúgbajà òṣèrébìnrin Yollywood, Ayo Adesanya tó jẹ́ wí pé kìí ṣe eré Yorùbá nìkan ló ń ṣe.

Ó jẹ́ òṣèré, olùdarí eré àti atọ́kùn pẹ̀lú tó máa ń fara hàn nínú eré lédè Yorùba, Igbo tó fi mọ́ Hausa.

Àkọlé fídíò,

Njẹ́ ẹ mọ̀ oé àlákálàá lè jẹ́ àfihàn aàrun ọpọlọ?

Ìlú Ijagun ní Ijẹbu ìpínlẹ̀ Ondo ló ti wá. Ó ka ìwé láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí tó fi kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Fásitì Ibadan nínú ìmọ̀ iṣẹ́ akàròyìn.

Ayo Adesanya bẹ̀rẹ̀ eré àgbéléwò ní ọdún1996 lẹ́yìn tó párí àgùnbánirọ̀ rẹ̀ kò tò dara pọ̀ mọ́ àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá.

Ó jẹ́ aya Goriọla Hassan tẹ́ll ṣùgbọ́n wọn kò sí papọ̀ mọ́.

Oríṣun àwòrán, @dayoamusa

Àkọlé àwòrán,

Dayo Amusa

Dayo Amusa

Temidayọ Amusa jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ogun tí a bí ní ìlú Eko, akọ́bí ọmọ márùn-ún ni. O jẹ Òṣèré, olóòtú, olùdarí àti olórin ọmọ Nàìjíríà.

Dayọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbo nìṣe ti Moshood Abiọla nínú ìmọ̀ ẹkọ́ Sáyẹ́nsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ oúnjẹ.

Ọdún 2002 ló bẹ̀rẹ̀ eré Tíátà tó sì ti fara hàn nínú ọpọ̀lọpọ̀ eré Nollywood ní ọ̀ àfín èdè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì.

Dayọ Amusa tún jẹ́ olùdarí ilé ìwé tírẹ̀.

Àkọlé fídíò,

'Mo ni baba isalẹ'

Oríṣun àwòrán, @Toyin Abraham/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Toyin Abraham

Toyin Abraham

Toyin Aimaku ló ń jẹ́ tẹ́lẹ̀. Ọmọ bíbí ìlú Auchi, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Edo ni.

A bí i ní ọjọ́ karùn-ún, osù kẹsan, ọdún 1984 sùgbọn ìlú Ibadan ní ìpínlẹ̀ Ọyọ ló gbé dàgbà.

Ó bẹ̀rẹ̀ eré síse ní ọdún 2003 nígba tí òsèré Tíátà Bukky Wright lọ se fíìmù kan ní ìlu Ibadan.

Láìpẹ́ yìí ló sẹ̀sẹ̀ gba òrùka 'sé oó fẹ mi' gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ pé "mó gbọ́, mo gbà" sì ìbéèrè olólùfẹ́ rẹ tuntun láti di aya rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, @wumitoriola

Àkọlé àwòrán,

Wunmi Toriola

Wunmi Toriola

Wunmi Toriọla jẹ́ òṣèré Tíátà ọmọ Nàìjíríà tó ń yára dìde nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò. Òṣèré, olóòtú àti oníṣòwò ni pẹ̀lú.

Ọmọ ìpínlẹ̀ Ogun ni. Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ìwé gíga fásitì ti Ilọrin nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ onírúurú èdè (Lingustics) ó sì tún gboyè Diploma nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Tíatà ní Odunfa Caucus.

Ní ọdún 2013 gangan ló gbérasọ. Ó bẹ̀rẹ̀ eré Tíátà rẹ̀ nínú eré 'Ìsẹ̀ṣe Làgbà' sùgbọ́n eré tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní di mọ̀lúmọ̀ká ni 'Ìwàkiwà'.

Ó ti fara hàn nínú eré tó lé ní àádọ́ta.

Wumi Toriọla ṣè ìgbéyàwó alárédè ní ọjọ́ kẹ́tàlá oṣù kárùn-ún ọdún 2018.

Láìpẹ́ ni Wunmi Toriọla bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí gbọ́nmi síì omi ò tó tó wáyé láàrin òun àti Toyin Abraham.

Àkọlé fídíò,

Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Oríṣun àwòrán, MERCY AIGBE/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Mercy Aigbe

Mercy Aigbe

Ọmọ ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edo ni Mercy Aigbe sùgbọ́n tí a mọ̀ bí ẹni ń mowó nínú àwọn eré elédè Yorùbá.

Ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní, ọdún 1978 ni a bí òṣèré Tíátà, olùdarí eré àti oníṣòwò yìí.

Ó lọ ilé ìwé Girama ní ìlú Eko, ilé ẹ̀kọ́ gbogbo nìṣe ti Ibadan ní ìpínlẹ̀ Ọyọ níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ìsúná.

Ní ọdún 2001, ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Tíátà ní ilé ìwé gíga fásitì ti Eko ó sì dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ Tíàtà lẹ́kùnrẹ́rẹ́ ní ọdún 2006.

Láìpẹ́ yìí ni Mercy Aigbe ra ilé àwòdami-ẹnu tí iye owó rẹ̀ tó igba mílíọ̀nù. Sáájú, ló si ilé iṣẹ́ tirẹ̀, Mag Divas Boutique tó ti ń ṣe aṣọ tó sì ń ta ọjà láti ọdún 2014.

Mercy Aigbe ṣègbéyàwó pẹ̀lú Lanre Gentry ní ọdún 2013 wọ́n sì ní ọmọ̀ méjì.

Oríṣun àwòrán, Jaye Kuti/Instagram

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Jaye Kuti

Jaye Kuti

A bí i ní ìlú Ilaro, ìpínlẹ̀ Ogun ní ọjọ́ kẹ́wàá, osù keje. Ó gbàgbọ́ pé gbogbo ìgbà lòun ń jẹ́ ọ̀dọ̀ tóun sì ń rẹwà sí i.

Òsèré Tíátà, onísòwò àti olóòtú eré ni. Òun ni alákòso àti adarí ilé isẹ́ fíìmù Jaylex Aesthetic Production.

Àkọlé fídíò,

Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?

Àkọlé fídíò,

Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ

Àkọlé fídíò,

'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ọ̀gá Bello: Ikú Aisha Abimbọla ká wa lára